Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Ọlọfa-Ina, gbajugbaja agba oṣere tiata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 4, 2024

Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Ọlọfa-Ina, gbajugbaja agba oṣere tiata


Wẹrẹ ni iroyin ibanujẹ naa jade sita lagboole awọn oṣere tiata lorileede Naijiria, nigba ti wọn sọ pe agba oṣere nni, Oloye Adedeji Aderẹmi ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ọlọfa-Ina ti jade laye.

Ọsibitu olukọni ti fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa niluu Ile-Ifẹ ni baba naa dakẹ si lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (74) gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Wọn ni aisan rampẹ lo kọlu Ọlọfa-Ina, to fi di pe wọn gbe e lọ si ọsibitu ọhun fun itọju.


Ọlọfa-Ina ti figba kan ri jẹ Ṣọbaloju ilu Ẹdẹ, oun si ni Majẹobajẹ tiluu Ẹdẹ ki ọlọjọ too de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI