Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun ti sọ pe akoko ti to bayii lati gbajumọ awọn iṣẹ idagbasoke, nitori gbogbo ọna lati le ma jẹ kijọba oun fọkan si isakoso oun ti kuna nitori bi oun ṣe jawe olubori ọhun.
Gomina sọ pe, Ireti wa ni pe gbogbo awọn alatako wa ti wọn pariwo pe ki atundi ibo waye le maa murasilẹ fun ọdun 2027. Niitori aṣeyọri yii ti fopin si gbogbo ọrọ ile-ẹjọ lati ọdun 2018''
O sọrọ yii ni papakọ ofurufu Gateway International, to wa niluu Ipẹru-Rẹmọ, lẹyin to pada de lati Abuja, nibi to ti jawe olubori nile-ẹjọ giga ju fun ti ibo gomina to waye lọdun 2023.
Bẹẹ lo wa ṣeleri pe ijọba oun yoo wa kọjumọ fifi awọn apẹẹrẹ rere lelẹ ati pe lati wakati yii lọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun, yoo bẹrẹ si jẹ anfaani mudunmudun ijọba pẹlu awọn eto rere to nii fun wọn.
Bakan naa lo waa fi idunnu ẹ han si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fun atilẹyin to ṣe foun lori irianajo oṣelu oun, bẹẹ naa lo tun dupẹ lọwọ ikọ awọn agbẹjọro ẹ, eyi ti Oloye Wọle Ọlanipẹkun ṣaaju fun.
O tun fi ẹmi imoore ẹ han si alaga ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ, Ọmọwe Abdulahi Umar Ganduje ati tipinlẹ Ogun, Oloye Yẹmi Sanusi, fun atilẹyin wọn ti o n ri gba latigba ti ọrọ oṣelu ti bẹrẹ.
Gomina Abiọdun tun dupẹ lọwọ igbimọ ẹlẹni marun-un ile ẹjọ giga julọ, eyi ti Onidajọ agba John Inyang Okoro, ṣaaju, igbimọ to gbẹjọ naa nipinlẹ Ogun ati nile ẹjọ kotẹmilọrun lori bi wọn ṣe ẹni tawọn eeyan n fẹ ko jẹ gomina wọn.
No comments:
Post a Comment