Alaṣẹ Adron Homes, EmmanuelKing ba Gomina Abiọdun yọ lori idajọ ile-ẹjọ to ga julọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 19, 2024

Alaṣẹ Adron Homes, EmmanuelKing ba Gomina Abiọdun yọ lori idajọ ile-ẹjọ to ga julọ

Emmanuel-King, Dapọ Abiọdun

Alaṣẹ ati oludasile gbajugbaja ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia lorileede Naijiria, Adron Homes Properties, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ti ba Gomina Dapọ Abiọdun, ti ipinlẹ Ogun yọ lori aṣeyọri ile ẹjọ to ga julọ,to sọ pe oun gan-an lo jawe olubori eto idibo gomina, tọdun 2023.

Lonii ni ile-ẹjọ to ga julọ gbe idajọ kalẹ wi pe Dapọ Abiọdun ni ojulowo gomina ti awọn araalu dibo yan nipinlẹ Ogun, ninu eto idibo to waye lọdun 2023.
 
Aarẹ Adetọla, ẹni to tun jẹ Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ tilẹ Rẹmọ nigba to n ba Gomina Abiọdun yọ lonii, ọjọ Ẹti, Furaide, o sọ pe aṣeyọri rere ni eyi jẹ, at pe yoo tun mu itẹsiwaju ba iṣẹ akanṣẹ to n lọ lọwọ.

O ni ipa rere ni Gomina Abiọdun ti fi lelẹ latigba to ti di gomina, ẹlu bo ṣe mu idagbsoke wọ ipinlẹ naa, ati eto ti yoo pese iṣẹ fawọn ọdọ, to fi mọ idagbasoke eto ọrọ aje to lọọrin.
 
Siwaju sii lo gba Gomina Abiọdun lamọran lati tubọ gbajugba awọn iṣẹ rere to ti bẹrẹ sẹyin, lẹyin to ti gba idajọ ile-ẹjọ to ga julọ, to si ti fopin si gbogbo hilahilo eto idibo.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe oun ti ṣetan lati tubọ ṣiṣẹ papọ pẹlu Gomina Abiọdun fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Ogun, leyi ti yoo jẹ ki eto ọrọ aje ni ilọsiwaju ju tu atẹyinwa lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI