Alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria ba ijọba ipinlẹ Ọyọ kẹdun idungbamu to ṣẹlẹ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 18, 2024

Alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria ba ijọba ipinlẹ Ọyọ kẹdun idungbamu to ṣẹlẹ n'Ibadan


Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ Gomina Ṣeyi Makinde kẹdun iṣẹlẹ ibugbamu to waye niluu Ibadan laipẹ yii.
 
Ninu lẹta ibanikẹdun ti Gomina AbdulRazaq tipinlẹ Kwara buwọ lu funra rẹ l'Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii lo ti sọ pe ẹdun ọkan niṣẹlẹ ọhun jẹ.
 
Nibẹ lo ti gba awọn to n wa kusa lamọran lati maa wa ọna aabo to peye loore-koore,, lati dẹkun ijamba ti yoo fi ẹmi awọn araalu ṣofo.
 
"Lorukọ awọn ara ipinlẹ Kwara, mo n fi lẹta yii ranṣẹ si awọn araalu ati ijọba ipinlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ ijamba ibugbamu to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii.
 
"Erongba wa ati ibanikẹdun wa, wa fun awọn araalu ati ijọba Ọyọ lasiko ipenija yii. Mo gbe oriyin fun akẹgbẹ mi, Gomina Ṣeyi Makinde ati ikọ rẹ lori igbesẹ oju ẹsẹ to gbe.
 
"Iṣẹlẹ yii tun ti fi ko awọn alakoso lọgbọn nipa bi wọn yoo ṣe maa wakusa wọn pẹlu awọn idaabobo to pe ye ni gbogbo igba.
 
"Ipe fun iwadii ohun to ṣẹlẹ yii pọn dandan lati mọ kulẹkulẹ bo ṣe ṣẹlẹ gangan, ki iru ré ma ba a tun ṣẹlẹ mọ
 
"A duro ti ijọba ati awọn ara ipinlẹ Ọyọ pẹlu bi wọn ṣe n bọ kuro ninu iṣẹlẹ to bani lọkan jẹ yii, a si gbadura pe ki Ọlọrun forijin awọn to jade laye, bẹẹ ni ki ilera pipe jẹ ti awọn to farapa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI