Gbajugbaja oṣere tiata nni, Aisha Lawal ti sọ pe bi ki ba a ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọrun to ko ohun yọ, ṣee ṣe koun naa ti jade laye nibi iṣẹlẹ idungbamu to waye niluu Ibadan lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii.
Aisha ni diẹ lo ku koun naa fi ara kaaṣa ijamba ọhun nibi toun ti lọ ra ẹran Suya niwaju ibi ti ijamba naa ti waye Bodija Housing Estate, Ibadan.
O ni
“Alhamdulilah fun ọjọ tonii, mo wa ni Bodija nigba ti iṣẹlẹ ibugbamu ọhun dun, koda, eti mi ṣi n ho yeeyeeyee titi di asiko yii.
“Mo dupẹ fun Ọlọrun lori aye wa. Mo gbe mọto mi si iwaju Estate naa lati ra Suya, ṣugbọn nigba to ya mo sun mọto mi siwaju kuro niwaju ile-ijo Sloggers si otẹẹli Metro ni adugbo Ọṣuntokun kan naa nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye.
“Ọlọrun ṣaanu oo. Ọpọ oku eeyan. Ki lo n ṣẹlẹ gangan?”
No comments:
Post a Comment