AFCON2023: Super Eagles foju Cameroon gbolẹ ṣakaṣaka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 28, 2024

AFCON2023: Super Eagles foju Cameroon gbolẹ ṣakaṣaka


Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orileede Naijiria, Super Eagles ti ko iya manigbagbe fun akẹgbẹ wọn, Indomitable Lions ti Cameroon.
 
AAmi ayo meji si odo ni ikọ Super Eagles fi bori Cameroon ninu idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ, 2023 Africa Cup of Nations to n waye lorileede Côte d'Ivoire.

Ademọla Lookman lo gba ayo mejeeji sawọn Cameroon pẹlu bi Victor Osimhen ati Calvin Bassey ṣe ran an lọwọ.
 
Ifigagbaga ọhun lo waye ni papa iṣere Stade Felix Houphouet-Boigny.
 
Ni bayii, Naijiria yoo wa koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Angola ninu ipele Quarterfinals.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI