Rasheed ji mọto gbe l'Abuja, Ibadan lọwọ ti tẹ ẹ, l'Adajọ ba sọ pe yoo ṣọdun lẹwọn ko to gba idajọ lọdun 2024 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 18, 2023

Rasheed ji mọto gbe l'Abuja, Ibadan lọwọ ti tẹ ẹ, l'Adajọ ba sọ pe yoo ṣọdun lẹwọn ko to gba idajọ lọdun 2024


Ile-ẹjọ Dei-Dei Grade 1 to wa niluu Abuja ti sọ pe ki derẹba, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Ridioam Rasheed ṣi lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn lori ẹsun wi pe o ji mọto gbe.

Rasheed, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni iroyin fi to wa leti pe o ji mọto kan ti wọn gbe si ikawọ rẹ gbe.
 
Niwaju Onidajọ Saminu Suleiman ni Rasheed ti jẹwọ pe lotitọ ni ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe iṣẹ eṣu ni.
 
Onidajọ Saminu Suleiman paṣẹ pe ki Rasheed ṣi wa lọgba ẹwọn Suleja titi di ọjọ karun, oṣu kinni, ọdun 2024 fun idajọ.

Ṣaaju asiko yii, agbefọba, 
Chinedu Ogada to tako Rasheed nile ẹjọ sọ pe Kenneth Eze to n gbe nipinlẹ Niger lo lọ fi to awọn ọlọpaa Zuba leti lọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Eze ni Rasheed wa sibi ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ, to si dọgbọn bi ẹni to fẹẹ ra ọkọ to din diẹ ni miliọnu meji (N1.7m) naira.

O ni ṣe ni Rasheed gba kọkọrọ mọto ọhun bi ẹni to fẹ ṣayẹwo bo ṣe n ṣiṣẹ si, to si ṣe bẹẹ gbe mọto ọhun salọ siluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Ilu Ibadan lọwọ ti pada tẹ ẹ, ti awọn ọlọpaa si ti lọ wa mọto naa pamọ si olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ẹlẹyẹle, Ibadan.
 
Ẹsun yii ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 312 ati 287.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI