Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara wi pe wọn fẹẹ ta otẹẹli Kwara gbọ, nitori pe ayederu iroyin pọmbele ni.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna f'ọrọ okoowo ati imọ ẹrọ, Ọnarebu Damilọla Yusuf gbe jade lọjọ Fraide to kọja yii lo ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ naa gbọ.
Yusuf ni atunṣe lo n lọ lọwọ lati le jẹ ki otẹẹli naa dun-un-wo laarin awọn akẹgbẹ rẹ lagbaye, ti yoo si tun di ibi igbadun fun awọn araalu.
O ni ọna ipa rere ti wọn ko gbọdọ gbe ta fun idi kan tabi omiranbi ko ṣe pe ki wọn tun un ṣe fun igbadun araalu ati ajoji to ba wọ ilu Ilọrin.
Yusuf tẹsiwaju pe oriṣiriṣi ayederu iroyin lo ti jade latigba ti ijọba ti gbe ipolowo sita ninu iwe iroyin Herald lọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan, ati iwe iroyin Tribune lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 nipa awọn ileeṣẹ to le ṣe atunṣe.
O ni latigba ti wọn ti ri ileeṣẹ to peregede ni iṣẹ atunṣe ti bẹrẹ ni pẹrẹu lai dawọ duro, to si ni iṣẹ naa ko ni pẹ ẹ pari.
No comments:
Post a Comment