Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe oun fọwọ sii ipolongo lati gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii.
Gomina AbdulRazaq lo sọrọ naa niluu Ilọrin, nibi ifilọlẹ ileeṣẹ ajọ to n gbogun iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC.
Nibẹ ni gomina ti sọ pe oun faramọ agbekalẹ Aarẹ Bọla Tinubu lori ipolongo lati gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii.
Ijọba Kwara la gbọ pe o ṣagbatẹru kikọ ọfiisi tuntun fun ajọ EFCC n'ipinlẹ naa, lati le mu ìpinnu ijọba apapọ ṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe ọfiisi tuntun naa yoo jẹ ki iṣẹ ya fun ajọ EFCC pẹlu irọrun lai laagun jinna.
Lara awọn to wa nibẹ ni adajọ agba Ọmọọba Lateef Fagbemi SAN; alaga EFCC, Ọla Olukoyede; adajọ agba Kwara, Onidajọ Abiọdun Adebara; awọn adajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun; Amofin Rotimi Oyedepo; Emir ilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari.
Awọn miran ni alakoso ẹka EFCC niluu Ilọrin, Michael Nzwekwe; Mutawali ilu Ilọrin, Ọmọwe Alimi AbdulRazaq; alaṣẹ Kam Holdings, Alaaji Kamoru Yusuf; oludasilẹ fasiti Al-Hikmah, Alaaji Abdulraheem Ọladimeji; ati awọn miran.
No comments:
Post a Comment