Ko si idibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP tun le bori mọ ni Kwara - Bọlaji Abdullahi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 11, 2023

Ko si idibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP tun le bori mọ ni Kwara - Bọlaji Abdullahi


Minisita tẹlẹri f'ọrọ eto ere idaraya ati awọn ọdọ lorileede Naijiria, Bọlaji Abdullahi ti sọ pe ko si idibo ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP tun le bori mọ n'ipinlẹ naa.

Abdullahi to jẹ oludije sipo aṣofin lati ẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ naa ninu eto idibo to kọja sọ pe iṣoro nla ni yoo jẹ fun ẹgbẹ naa lati gbe oun gidi ṣe ninu eto idibo odun 2027.

Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Abdullahi sọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin Punch.

O ni ogun inu ile lo n ja ẹgbẹ oṣelu PDP fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin, to si jẹ ko rẹ wọn, ati pe o jẹ agbegbe ti ọta le ba wọle si wọn lara, nigba ti ẹgbẹ APC de.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe "Ọdun 2027 ṣi jinna, ọpọ iṣẹ ni wọn nilo lati ṣe yala lati ipinlẹ ni tabi apapọ. Ọpọ atunto lo ni lati waye ki ẹgbẹ naa le padabọ sipo nibi to ti le du ipo agbara.

"Ni asiko ti a wa yii, mo ro pe ipo ti wọn wa ko dara rara."

O tẹsiwaju pe "Mo ro pe ẹgbẹ na ti ohun ti wọn fi n ṣe agbara nu. Ẹgbẹ naa jẹ gaba fun ọpọlọpọ ọdun lai ni alatako tẹlẹ. 

"Ẹ ranti igba ti alaga ẹgbẹ naa tẹlẹri, Oloye Vincent Ogbulafor, sọ pe PDP yoo ṣakoso Naijiria fun ọgọta ọdun. Nigba to sọrọ yii, PDP lo n jọba lọwọ, to si fẹẹ dabi ẹni pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo ni Naijiria ni.

"Wọn jẹ gaba yẹn debi wi pe PDP jẹ ọna kan ṣoṣo to de ipo agbara. Ifigagbagba, ilakaka ati ijakadi laaarin oludije lẹgbẹ naa wa lagbara.

"Koda, awọn ti wọn fi ọwọ ọla gba loju ti inu n bi ko le fi ẹgbẹ naa silẹ lọ si ẹgbẹ miran."

"Wọn ko ṣagbekalẹ PDP lati jẹ ẹgbẹ alatako, idi niyẹn to fi jẹ pe lati ọdun pipẹ ti wọn ti n jẹ ẹgbẹ alatako, niṣe lo m dabi ẹni pe wọn n lakaka lati ri afẹfẹ fi min."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI