Ile igbimọ aṣofin Kwara buwọ lu ọmọ igbimọ iwadii ENDSARS gẹgẹ bi Kọmiṣanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 22, 2023

Ile igbimọ aṣofin Kwara buwọ lu ọmọ igbimọ iwadii ENDSARS gẹgẹ bi Kọmiṣanna


Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ti fi ontẹ lu Omidan Nafeesah Buge to ti figba kan ri jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ iwadii ENDSARS gẹgẹ bi Kọmiṣanna ni ipinlẹ.

Buge to wa lati ijọba ibilẹ Baruten ni wọn buwọ lu lẹyin akitiyan rẹ lori aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ninu eto idibo apapọ to kọja.

Olori ile igbimọ aṣofin ọhun, Yakubu Salihu Danladi lẹyin ti wọn fontẹ lu Buge wa paṣẹ pe ki agbọpa, Alaaji Abdul-kareem Ọlayiwọla Ahmed lọ fi to gomina leti.

Nafeesat Buge jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ iwadii si ifẹhonuhan ENDSARS, bẹẹ lo tun jẹ ọmọ igbimọ kotẹmilọrun fun ile igbimọ aṣofin Niger

Bakan naa lo tun jẹ akọwe ẹgbẹ Grass Root Engagement and Orientation North Central ti ipolongo Tinubu/Shettima Presidential Campaign Council.

O tun jẹ akọwe fun Kwara North Development Council (KWANDCO). 

Ninu iroyin miran, wọn tun ti da Ọnarebu Musa Atoyebi ti ẹgbẹ oṣelu APC to ṣoju ẹkun Odo-Ogun pads lẹẹkeji.

Eyi lo waye lẹyin ti ile ẹjọ da a lare gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin Kwara to wọle idobo tako Otunba Taiwo Afolabi ti ajọ Independent National Electoral Commission ti kọkọ kede.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI