Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara ti ju gbajugbaja tọọgi ti wọn lo n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ naa, Abọlaji Shafii, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ojulari sẹwọn ọdun mẹwaa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ati nini ibọn lọna aitọ ni awọn ileeṣẹ ọlọpaa fi kan Ojulari niwaju ile ẹjọ.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kini, ọdun 2023 ni ọwọ tẹ Ojulari lasiko to fẹẹ da ipolongo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti wọn ṣe ni wọọdu Oju Ẹkun Sarumi ru.
Ibọn ilewọ meji ati ọta ibọn ni wọn gba lọwọ rẹ ni kete ti akara rẹ tu sepo.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Mahmoud Abdulgafar Gafar sọ pe awọn ẹri toun ri gba fi han daju pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun to ti dunkooko mọ ẹmi awọn eeyan ni Ojulari.
Onidajọ Gafar sọ pe Ojulari ko yẹ lẹni to n gbe laarin awujọ lasiko yii, to si paṣẹ pe ko lọ kẹkọọ lọgba ẹwọn fun ọdun mẹwaa pere.
No comments:
Post a Comment