Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pin awọn ẹrọ amunawa 'tiransifọma' fun awọn agbegbe marun-un ọtọọtọ ni ipinlẹ naa.
Eyi ni lati mu ilọsiwaju ba eto ọrọ aje awọn agbegbe wọnyi, gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ ohun agbara, Rukayat Abdulhameed fi sita laipẹ yii.
Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna f'ọrọ ohun agbara, Onimọ-ẹrọ Kọla AbdulAzeez AbdulGaniy nibi eto ti wọn ti fa awọn tiransifọma naa le awọn araalu lọwọ, o ni yoo ṣe anfaani pupọ fun wọn.
Lara awọn agbegbe naa ni Balogun to wa ni Tanke Oke-Odo, ijọba ibilẹ Guusu Ilọrin; College of Arabic and Islamic Legal Studies (CAILS), ijọba ibilẹ Ilorin West; Gerewu to wa ni ijọba ṣetan ibilẹ Ilorin West.
Awọn yooku ni agbegbe Reke ati Gbale Asun ti wọn wa ni ijọba ibilẹ Asa.
No comments:
Post a Comment