Ijọba Kwara gbe nọmba sita fawọn onibara to n lo omi ẹrọ igbalode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 6, 2023

Ijọba Kwara gbe nọmba sita fawọn onibara to n lo omi ẹrọ igbalode


Lojuna lati jẹ ki awọn araalu maa jẹ igbadun omi ẹrọ igbalode lai mi idakureku ninu, ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe nọmba ẹrọ ibanisọrọ sita fun awọn eeyan.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ omi ẹrọ igbalode ni Kwara, Adamu M. Saidu fi sita laipẹ yii lo ti ni ijọba ṣetan lati tan iṣoro ti araalu n dojukọ lori lilo omi ijọba.

O ni Kọmiṣanna f'ọrọ omi ẹrọ igbalode, Ọnarebu Usman Tunusa Lade lo fidi rẹ mulẹ ni ọfiisi rẹ, lati jẹ ki araalu mọ pe ijọba ka wọn kun, ati lati tan iṣoro wọn.

Nibẹ lo ti gbe oriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori igbesẹ yii, to si ni yoo fun araalu ni anfaani lati sọ ẹdun ọkan wọn fun ijọba.

O ni oniruuru ohun ti araalu ba fẹẹ fi to ijọba leti nipa ọrọ omi ẹrọ igbalode, yala omi ko yọ daadaa, ọpa omi bẹ lagbegbe wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ ki wọn fi to wọn leti lori awọn ẹrọ ibanisọrọ ọhun.

Awọn ẹrọ ibanisọrọ naa ni 07000059928 ati 08121449777

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI