Gbajugbaja puromota nni, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ajiki-Olu ti ṣetan lati fi ẹbun ọdun ta awọn akẹkọọ lọrẹ niluu Abẹokuta.
Oloye Ajiki-Olu to ti gbe ọpọ awọn olorin Fuji, Musulumi ati bẹẹbẹẹlọ, to fi mọ awọn oṣere tiata dide lorileede Naijiria lo fẹẹ fi ẹbun ọdun ta awọn akẹkọọ ile-ẹkọ to ti jade, iyẹn Anglican High School lọrẹ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni ọkunrin naa fẹẹ fi ẹbun ọdun yii tọrẹ.
Ninu ọrọ ti ẹnikan to sunmọ Ajiki-Olu, ẹni to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri ṣe sọ, O ni kii ṣe akọkọ ree ti ọkunrin naa yoo maa ta awọn eeyan lọrẹ.
Ẹni naa sọ pe lara awọn ohun ti Ajiki-Olu fẹran ni lati maa ta awọn alaini tabi awọn to ku diẹ kaato fun lọrẹ, eyi lo fa a to fi pinnu lati fẹmi imoore han si Ọlọrun nipa fifi ẹbun ọdun tọrẹ f'awọn eeyan.
Akẹkọọ ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta ni yoo jẹ anfaani ẹbun ọdun yii gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ati pe awọn nnkan bi ounjẹ, owo ati dukia ni Ajiki-Olu yoo fi tọrẹ lọjọ naa.
Nigba toun funra rẹ n fidi rẹ mulẹ, Ajiki-Olu sọ pe lara iṣẹ ti Ọlọrun fi ran oun ni aanu ṣiṣẹ, ati pe o jẹ ọna ti Adẹdaa fi n bunkun oun, to si n mu ki ileeṣẹ oun maa tẹsiwaju ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment