Gbajumọ oṣere tiata, Dejumọ Lewis jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 23, 2023

Gbajumọ oṣere tiata, Dejumọ Lewis jade laye


Gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Dejumọ Lewis ti jade laye lẹni ọgọrin ọdun.
 
Ọkan lara awọn agba oṣere nni, Saidi Balogun lo kede ipapoda Lewis lonii, ọjọ Abamẹta, Satide lori ikanni ayelujara Instagram rẹ.
 
Saidi Balogun nigba to n sọrọ sabẹ fọto oloogbe naa, o kọ ọ pe "O daarọ DEJUMỌ LEWIS, ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹgẹ rere. Sun re."
 
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii gbọ nipa iru iku to pa agba oṣere naa, ṣugbọn wọn ni aisan to ni ṣe pẹlu ọjọ ogbo lo kọlu.
 
Ilu mọ ọn ka ni Lewis jẹ ninu fiimu agbelewo lorileede Naijiria.
 
Oun si lo ko ipa Kabiyesi ninu gbajumọ fiimu The Village Headmaster ti wọn ṣafihan rẹ lori tẹlifiṣan NTA laaarin ọdun 1968 si 1988.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI