Ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Katsina ti sọ pe ọwọ awọn tun ti pada tẹ awọn ẹlẹwọn meji ti wọn n reti ọjọ idajọ, ṣugbọn ti wọn na papa bora.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni ileeṣẹ ọgba ẹwọn sọ pe awọn mejeeji naa salọ kuro ni Medium Security Custodial Centre to wa ni Katsina.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, ASC Najibullah Idris fi sita l'Ọjọru, Wẹside, o ni kete ti awọn mejeeji yii ti salọ l'awọn ti fi to awọn eleto aabo yooku leti fun iwadii.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, ASC Najibullah Idris fi sita l'Ọjọru, Wẹside, o ni kete ti awọn mejeeji yii ti salọ l'awọn ti fi to awọn eleto aabo yooku leti fun iwadii.
O ni ẹlẹwọn akọkọ to kọkọ salọ, Ibrahim Muhammad Lawal ti wọn tun n pe ni Abba Kala lọwọ kọkọ tẹ nipa iranlọwọ awọn eleto aabo.
Idris ni irinṣẹ igbalode lawọn fi mu Lawal nibi to lọ farapamọ si.
Bakan naa lo sọ pe ẹlẹwọn keji, Musa Isah toun naa salọ pẹlu, irinṣẹ igbalode naa lọwọ fi tẹ ẹ niluu Kaduna lọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2023.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn mejeeji ni wọn ti da pada sẹwọn ti wọn wa, ati pe wọn tun ti bẹrẹ sii ṣọ wọn ju ti tẹlẹ lọ, ki wọn ma ba a raaye salọ.
No comments:
Post a Comment