Minisita tẹlẹri fọrọ epo rọbii lorileede Naijiria, iyẹn lasiko iṣakoso Arẹ Goodluck Ebele Jonathan, Diezani Alison Maduekwe to salọ UK ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ lati foju aanu wo oun lati pada siluu.
Madueke lo salọ si UK ni kete ti iṣakoso Jonathan dopin lati le sa fun iwadii lori ẹsun jibiti owo ti wọn fi kan an.
Ninu atẹjade ti ajọ EFCC gbe jade, wọn ni Diezani to n la ipele keji arun jẹjẹrẹ kọja ti n rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bọla Ahmẹ Tinubu lati pada wa si Naijiria.
EFCC ni Diezani loun ti ṣetan lati jẹwọ gbogbo iwa jibiti toun ṣe lasiko toun wa nipo gẹgẹ bi minisita fọrọ epo rọbii.
Diezani lasiko to n dahun ibeere lọdọ awọn akọroyin niluu London, o ni oun ti ṣetan lati jẹwọ gbogbo bi ọrọ owo jibiti ti wọn fi ẹsun rẹ kan oun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, obitibiti owo to le ni biliọnu owo dọla ni wọn fi kan Diezani wi pe o ko jẹ, ti ko si ṣalaye nigba naa, ko to di pe o na papa bora.
“Mo ti gba Jesu gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala mi. Bi mo n ba a yin sọrọ yii, mo n la ipenija ipele keji arun jẹjẹrẹ kọja, eyi ti eleto ilera mi gba mi lamọran pe mo gbọdọ maa ṣayẹwo, ki n si maa loogun loore-koore titi ayeraye mi.
“
Bẹẹni, ko si ẹni to pe, ṣugbon nigba miran, Ọlọrun maa n gba awọn nnkan laaye lati ṣẹlẹ. Wọn ti fi ẹsun iṣowo kumọkumọ kan mi nigba ti mo wa gẹgẹ bii minisita fọrọ epo rọbii, to si jẹ pe otitọ ni.
“Ṣugbọn maa fẹ ki Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ati gbogbo ọmọ Naijiria fori jin mi lati pada wa sile, ki n si wa ko ipa temi nitori pe iwọnba lo ku ki n lo laye."
Siwaju sii ni atẹjade EFCC tun ka pe
“Ọkọ mi ati gbogbo mọlẹbi mi, to fi mọ awọn agbẹjọro mi lorileede Naijiria ati ni United Kingdom mọ nipa ajọṣepọ mi pẹlu Gomina ipinlẹ Zamfara lọwọlọwọ, ẹni ti mo ko biliọnu mẹsan owo dọla fun lati tọju rẹ nigba to wa ni alakoso nile ifowopamọ First Bank Nigeria PLC.
“O ṣeni laanu wi pe o ti wa di pe Ọgbẹni Dauda Lawal ko wa gbe ipe mi mọ, to si tun jẹ pe niṣe lo n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ọlọpaa UK lati maa ṣọ mi kaakiri, boya lati le sọ gbogbo owo naa di tiẹ nigba ti mo ba ku tan."
No comments:
Post a Comment