Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti foju awọn ibeji meji kan, Hassan Nurudeen, ati Hussien Nurudeen, ti wọn jẹ ọmọ ogun ọdun ba ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Badagry.
Awọn mejeeji yii ni iroyin fi to wa leti pe wọn pawọpọ lu oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ti Eko Electricity Distribution Company (EKEDC) meji.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ ti wọn lo niiṣe pẹlu biba nnkan jẹ, lilu eeyan ati ikọlu eeyan lọna aitọ ni wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ Fadahunsi Adefioye lọjọ Aje, Mọnde, oni.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun ti a wa yii ni wọn sọ pe awọn mejeeji lu oṣiṣẹ ileeṣẹ EKEDC Lamidi Akeem pẹlu okuta ati igi, ti wọn si fọ oju osi rẹ kan.
Adugbo ti wọn pe ni Evangelist Bello David, Aradagun, Badagry ni wọn ti lu ọkunrin naa ni nnkan bi agogo meji ku iṣẹju marundinlọgbọn ọsan.
Yatọ si pe wọn lu, wọn tun ba foonu Samsung Galaxy A41 ti owo rẹ to N153,000 to jẹ ti Enemwo Clement, oṣiṣẹ EKEDC.
Nigba to n sọrọ, Onidajọ Fadaunsi Adefioye sọ pe ki ẹnikọọkan wọn lọ san ẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bi owo beeli wọn pẹlu oniduro meji-meji.
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni, ọdun 2024.
No comments:
Post a Comment