Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ajọ alaanu nla kan ti wọn pe ni Ọkọ Opo lati lalẹhu n'ipinlẹ Ogun lakọtun, eyi ti awọn Opo to ti padanu ọkọ wọn yoo ti jẹ anfaani iranwọ.
Gbajugbaja oniṣowo ilẹ ati dukia n'ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Babatunde Adeyẹmọ to jẹ alaṣẹ ati alakoso ileeṣẹ Pelican Valley Estates Limited lorileede Naijiria lo gbe ajọ yii kalẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2023 ni wọn yoo ṣiṣọ loju ajọ naa ninu gbọngan The Podium to wa ninu ọgba Cpsy Pelican Valle, Laderin niluu Abẹokuta.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, kii ṣe Opo nikan ni yoo maa jẹ anfaani ninu ajọ alaanu yii, bi ko ṣe awọn ọmọde, to fi mọ awọn to ku diẹ kaato fun laarin ilu.
Wọn yoo ṣafihan eto ọhun ti yoo waye laarin agogo mẹsan owurọ si agogo mẹwaa ku iṣẹju mẹẹdogun, owurọ ọjọ naa lori ikanni ayelujara ileeṣẹ naa.
Gbajugbaja akọroyin nni, Eddie Aina; Tọpẹ Daramọla to jẹ ogbontarigi sọrọsọrọ, Ọgbẹni Lanre Jaji ati Ọgbẹni Ernest Nwokolo to jẹ akọroyin ileeṣẹ iwe iroyin The Nation ni yoo tukọ eto ọjọ naa.
Awọn igbimọ alakoso ajọ alaanu yii bii Ọgbẹni James Ọlaṣẹinde ti ọpọ awọn ololufẹ tuata mọ si Pa James yoo wa nikalẹ lọjọ naa.
Ọjọgbọn Adeyẹmọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni awọn ti yoo tukọ eto naa yoo sọ ọjọ iwaju ati ipinnu ajọ ọhun fawọn eeyan.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn Opo ti ko din ni ọgọrun kan (100) ni yoo jẹ anfaani ajọ naa , bẹẹ ni wọn yoo tun gba idanilẹkọọ nipa ọjọ ogbo, aisan ọjọ ogbo ati awọn nnkan miran.
Ogbontarigi onimọ nipa ilera, Lanre Jaji ni yoo ṣe idanilẹkọọ nipa ọjọ ogbo, bakan naa ni Iya Adinni Musulumi ti Ginti to wa niluu Ikorodu, Alaaji Sidikat Adeyẹmọ naa yoo tun sọrọ nipa iriri rẹ gẹgẹ bi Opo fun awọn alejo.
O ni lẹyin eto naa, awọn Opo yoo lọ sile pẹlu oriṣiriṣi ẹbun bii oúnjẹ ati owo, bakan naa ni eto irinna ti wa nilẹ fun awọn to ba wa nibẹ.
No comments:
Post a Comment