Agba oṣere tiata, Ṣeyi Crown fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọ-ibi ọgọta ọdun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 13, 2023

Agba oṣere tiata, Ṣeyi Crown fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọ-ibi ọgọta ọdun l'Abẹokuta


Gbogbo eto lo ti n lọ lọwọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun gbajugbaja oṣere tiata nni, Ọmọọba Adeleke Patrick Adetutu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ṣeyi Crown.

Ilu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun ni eto ayẹyẹ ọjọ ibi naa yoo ti waye l'ọjọ kọkandinlọgbọn , oṣu keji, ọdun 2024.

Gbọngan ayẹyẹ Excellent, iyẹn Excellent Event Centre to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, bẹrẹ lati agogo mejila ọsan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Alaaji Sule Alao Malaika ni yoo dalu bolẹ lọjọ naa, nigba ti Ọdunlade Adekọla ati Fathia Williams yoo dari eto ọjọ naa.


Gomina ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN n'ipinlẹ Ogun, Kọmireedi Owolabi Ajasa ni olugbalejo ọjọ naa, ti awọn bii 

Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Kọmireedi Bọlaji Amuṣan ti awọn eeyan mọ si Mista Latin ati agba olorin nni, Alaaji Ṣẹfiu Adekunle Alao ti awọn eeyan mọ si Baba Oko ni olugbalejo agba fun ọjọ naa.

Gẹgẹ bi Ṣeyi Crown funra rẹ ṣe gbe e sori ikanni ayelujara ti Facebook rẹ, o jẹ ko di mimọ pe aṣọ Kampala ni tikẹẹti tawọn eeyan yoo fi wọle si gbọngan lọjọ naa.

O ni awọn bii Owolabi Ajasa, Fẹmi Ṣolaja ati Alaaja Yinka ni wọn wa ni akoso aṣọ tita ati rira fun awọn to ba fẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI