Onidajọ N. U. Sadiq ti ile-ẹjọ giga to wa nipinlẹ Kaduna ti ju gendekunrin mẹrin kan sẹwọn ọdun marun-un gbako, lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo'.
Awọn mẹrin naa, Chinedu Prince Omeka, Adamu Eric Mendos, Daniel Andrew, ati Elom Vincent Prince.
Ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan wọn ni pipe ara wọn ni orukọ ti wọn ko jẹ lati fi lu jibiti.
Awọn mẹtẹẹta ni wọn jẹwọ pe otitọ ni, ati pe awọn gba wi pe awọn jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan awọn.
Bi wọn ṣe jẹwọ ni awọn agbefọba to tako wọn, M.U Gadaka ati M. Lawal rọ ile ẹjọ lati gbe idajọ ododo kalẹ lori wọn.
Onidajọ Sadiq ju awọn mẹta sẹwọn ọdun meji-meji tabi ki wọn san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.
Elom Vincent naa ni wọn ju sẹwọn ọdun mẹta gbako tabi koun naa san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.
No comments:
Post a Comment