Ṣolẹyẹ, Ọpalẹyẹ ṣe pupọ ninu idagbasoke Naijiria - Gomina Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 22, 2023

Ṣolẹyẹ, Ọpalẹyẹ ṣe pupọ ninu idagbasoke Naijiria - Gomina Abiọdun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ṣapejuwe alakoso eto iṣejọba ologun nipinlẹ Ondo nigba kan ri, oloogbe Ọgagun Ẹkundayọ Ọpalẹyẹ gẹgẹ bi ọkan pataki lara awọn to kopa ribiribi ninu idagbasoke ati ilọsiwaju orileede Naijiria.
 
Abiọdun lo sọrọ yii niluu Abẹokuta lasiko to ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlẹbi oloogbe naa nile rẹ to wa lagbegbe Ibara GRA.

O ni lara awọn to ja fitafita pẹlu ọkan akikanju lati rii pe Naijiria de ilẹ ileri ni oloogbe Ọpalẹyẹ nigba aye rẹ, paapaa lasiko to wa nijọba.
 
Gomina ọhun ni lara awọn awokọṣe pataki fun awọn ọdọ Naijiria ni orileede ni oloogbe yii jẹ, to si ni awọn ko le gbagbe ipa rere to ti ko nigba aye rẹ.
 
Bakan naa ni ti minisita tẹlẹri fọrọ eto iṣuna ni Naijiria, Oloye Ọnaọlapọ Ṣolẹyẹ, gomina sọ pe lara awọn ti Naijiria ko le gbagbe ni oloogbe naa.
 
Minisita fọrọ eto iṣuna ni Oloogbe Ṣolẹyẹ lasiko iṣejọba Ọgagun Mohammadu Buhari nigba ologun.

O ni ipa rere to fi silẹ ko to ku lawọn ko le gbagbe, pẹlu bo ṣe ni ẹni to yẹ ki awọn eeyan maa ṣamulo awọn ọgbọn ati imọ idari rẹ ni oloogbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI