Gbajugbaja agba oṣere Yoruba nni, Alagba Oluṣẹgun Kẹhinde Aderẹmi Akinrẹmi, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ tiata mọ si Chief Kanran ti sọ pe o to ọgbọn ọdun toun ti wa nidi iṣẹ tiata ko to di pe okiki oun bẹrẹ sii tan kaakiri agbaye.
Kanran lo sọrọ yii lakoko to n ba ikọ ẹgbẹ akọroyin lede Yoruba sọrọ nibi ifọrọwerọ ti wọnn ṣe fun un laipẹ yii, nibẹ lo si ti tu pẹrẹpẹẹrẹ ọrọ kalẹ.
Ẹ ka bi ifọrọwerọ naa ṣe lọ si...
Orukọ yin lẹkunrẹrẹ
Orukọ mi ni Oluṣẹgun Kehinde Aderẹmi Akirẹmi tawọn eeyan mọ si Oloye Kanran
Mo wa lati ilẹ Ọmọ Yoruba tori bi a ṣe ni ile baba naa ni a tun ma ni ile iya, ati ọtun ati osi mi, ilẹ Yoruba ni mejeeji. A bi mi nilu Eko, mo si kawe yanju l’Ekoo ṣugbọn bi mo ba fẹ dahun ibeere yin daadaa,ọmọ bibi ilu Abẹokuta nimi bẹẹni mo tun tan mọ ilu Ile-Ifẹ.
Bawo lẹ ṣe bẹrẹ gan-an?
Mo bẹrẹ irinajo ileewe mi ni St Paul Primary School,Idi-Oro ni Mushin, mo lọ sileewe girama Eko boys High School ṣugbọn Kings College ni mo pada pari irinajo girama si. Lẹyin naa ni mo tẹsiwaju lọ sẹka ẹkọ imọ aṣa iyẹn ni Yunifasiti Eko,nibẹ ni mo ti pade awọn Ọjọgbọn bii Wọle Ṣoyinka, Akinnugba, Dapọ Adelugba,Ọjọgbọn Bọde Ọsanyin atawọn mi-in, ti wọn ba ṣiṣẹ diẹ ni Yunifasiti Ibadan ati ti Ile-Ifẹ,wọn a dari pada s’Ekoo. Ni yunifasiti naa ni mo ti pada ẹgbọn mi kan torukọ ẹ n jẹ Ayanfẹmi Oroniyi Philips, oun n ṣiṣẹ nibẹ nigbayẹn,oun naa lo da ẹgbẹ oṣere ‘Oṣumare theatre troupe’ silẹ,ẹni ti mo n sọ yii ni ọkọ gbajumọ oṣere torukọ ẹ n jẹ Idowu Philips tawọn eeyan mọ si Iya Rainbow.
Fẹmi Philips lo n kọ awọn ọmọ Yunifasiti nilu nigba naa, nibẹ ni emi ati ẹgbọn mi Yẹmi Rẹmi lẹka ẹkọ ere tiata ,awọn Ọjọgbọn to wa nibẹ naa lo ni ka lọọ tẹsiwaju ninu ẹkọ wa.
Loootọ ni ẹ ti lorukọ nidii iṣẹ tiata ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii,ao fi bẹẹ ri ki wọn pe yin sere, ṣe ẹ ṣẹ awọn kan ni abi ẹyin lẹ ni ki wọn ma pe yin si lokesan?
Ọrọ yin ko ni daru, akọọkọ; mo le fi gbogbo ẹnu sọ pe wọn dẹyẹ si mi nigba kan, ṣẹ ẹ mọ pe anjuwọn o ṣee wi lẹjọ, ija ilara o tan bọrọ. Lasiko kan ni wọn ma n ni ṣe oun nikan ni. Lati kekere mi ni mo ti bẹrẹ orin kikọ ni ṣọọṣi ti mo si ma n wo ere awọn baba Hubert Ogunde, Duroorikẹẹ Ladipọ, Oyin Adejọbi. Ẹ jẹ ki n dẹrin kan pa yin, lọjọ kan ni mo fẹẹ mọ bawọn eeyan gigun ṣe n wọnu apoti ti wọn pe ni tẹlifiṣan, ni mo ba tilẹkun mọri, mo yọ ọbẹ tii ṣugbọn pabo ni akitiyan mi jasi toripe waya lasan ati abọ funfun kan bayii ni mo ba lẹyin ẹ. Aluki ni wọn fi mi ṣe lọjọ naa ṣugbọn mo pinnu siwaju sii lati ṣiṣẹ tiata to n gbe ẹni gigun wọnu apoti to wa ninu palọ wa.
Bawo ni Kanran ṣe wa pada darapọ mọ awọn oṣere tiata?
Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju, mo pade Oloogbe Fẹmi Oroniyi Philips ni Yunifasiti Eko, baba lo jẹ simi nidi iṣẹ yii, agba ọjẹ oṣere naa ni mo ba ṣe ere kan ti redio ipinlẹ Eko bẹẹ lọwọ fun nibẹ ni mo ti mọ ibi tawọn eeyan n gba dẹnu tẹlifiṣan, aṣe maṣinni lo n ṣiṣẹ kii ṣe pe awọn eeyan n ko sinu ẹ. O to ọgbọn ọdun timo ti wa lẹnu iṣẹ tiata ki n to rọwọ mu, bo tiẹ jẹpe gbogbo ẹka to wa ninu iṣẹ tiata ni mo ti kọ nipa nileewe.
Ẹ jẹ ka sọ nipa ilara tẹẹ mẹnuba yẹn, bawo lo ṣe wọle?
Mo jẹ ẹnikan to ja fafa nidi iṣẹ ti mo yan laayo, bi Fẹmi Philips ba ti fun wa niṣẹ, loju-ẹsẹ ni mo ti ma ṣe agberu gbesọ, iyẹn ma n bi awọn eeyan taa jọ wa nigbayẹn ninu lọtọ toripe o ma n gba wọn to oṣu kan si meji ki wọn to le ka akasori yẹn, ibiti ilara kọkọ gba wọle niyẹn ṣugbọn sibẹ mo tẹramọ nnkan ti mo n ṣe. Lasiko naa tun ni Oloogbe Lateef Jakande, Gomina ipinlẹ Eko nigba yẹn pinnu lati da redio silẹ, ibi ti wọn pe ni ile ibudo aṣa bayii iyẹn Lagos State Council for Arts and Culture ni redio naa wa nigbayẹn. Jakande lo bẹ Fẹmi Philips lọwẹ pe ko ya iṣẹ akanṣe to maa sọ nipa aṣa iṣẹmbaye, mo kopa to pọ ninu ẹ. Nnkan nla ni o; koda pẹlu aiya ara ni ọga wa fi ya iṣẹ yẹn tori naa ko ju oṣu keji taa ya iṣẹ yẹn tan ni Fẹmi Oroniyi Philips jade laye. Iku ọkunrin naa dun mi gidi toripe o fẹran mi, bi o ba ṣe Ọba emi a ṣe Baṣọrun, loootọ ni mi o gbowo ninu iṣẹ yẹn ṣugbọn mo mọ pe ko ba ọfẹẹ de.
Ṣe ẹyin o beere owo ni abi ẹ beere wọn o fun yin?
Ta lo n jẹun ti aja n juru, ṣe niṣoju ina ni ewura ti n hurun, ko ṣẹni to gboju gboya lati beere owo iṣẹ lọwọ ọga nigba naa, koda ṣeni inu wa ma n dun ṣẹnkẹn pe wọn pe wa siṣẹ atipe wọn ti jẹ ko ye wa pe orukọ ni keeyan kọkọ le ko to ma le owo toripe orukọ lo n bi owo. Gbogbo ẹnu ni mo fi sọ ọ,ko sẹni ti Oloogbe Ogunnde ma pe siṣẹ to maa beere owo, ṣe lo ma duro de igba ti baba ma fun lowo. Kikopa ninu ere Ogunnde nikan jẹ iwuri lọtọ koda iwọ gan o nii ranti beere owo
Ọna wo lẹyin wa gba lorukọ nidi iṣẹ tiata?
Bẹo ba gbagbe, mo ni aisan n ṣe ẹgbọn mi Ayanfẹmi Oroniyi Philips lasiko ti a n ya ere ti Jakande ni ka ya, ko sẹni to ri tọlọjọ ṣe o, araba nla ya niju, baba Oṣumare pajude bẹẹ wọn ti n ṣafihan iṣẹ taa ya lọwọ, ko tun ju oṣu meji ni ileeṣẹ redio jona. Ibi ti irinajo mi lati di olokiki ti bẹrẹ niyẹn. Ileeṣẹ redio ranṣẹ si Oṣumare theatre troupe ki wọn wa tun ere naa ya, ibẹ ni idanrawo ti bẹrẹ tawọn Ọjọgbọn nidi iṣẹ yii bii,Alagba Jimi Odumosu,Rẹmi Babalọla atawọn eekan mi-in ti tọka mi gẹgẹ bi ẹni to dantọ julọ niyẹn.
Awọn oṣere wo lẹ jọ wa nibẹ nigba yẹn?
A pọ diẹ o,awọn bii Tajudeen Gbadamọsi ẹni tawọn eeyan n pe ni Coach, ọkunrin ti mo n sọ yii mọṣẹ yii doju amin, o le jo, o le kọrin,Alade Eko naa wa nibẹ,Kafila Agodongbo,Ṣẹgun Faloni, Oloogbe Leke Ajao tawọn eeyan mọ si Kokosari nigbayẹn, o ti da ẹgbẹ oṣere tiẹ silẹ bo ṣe kuro lẹyin Fẹmi Philips ṣugbọn gbogbo wọn pada wa lasiko igbaradi yẹn,emi lo pada ja mọ lọwọ. Mo fi gbogbo emi mi ṣe iṣẹ yẹn koda awọn eeyan gboṣuba fun mi, wọn ni ṣe lo dabi ẹnipe Oloogbe Fẹmi Philips ko sinu mi. Bawọn eeyan ṣe bo mi nita gbangba ti wọn fẹẹ ma so mọ mi ti wọn n pariwo Kanran,lo jẹ ki n mọ pe mo ti di gbajumọ.Latigba yẹn ni mo ti bẹrẹ sii ṣere loriṣiiriṣii.
Njẹ ẹ le sọ nipa nnkan tẹyin ro pe o le fa ilara?
Gẹgẹ bi nnkan ti mo hu gbọ, wọn ni mo n ṣe igberaga bẹẹ tiwọn naa ni mo n ṣe atipe ao le sọ pe a fẹ fi ere wa kọ awọn eeyan lẹkọọ ko tun wa jẹ awọn taa fẹ kọ lẹkọọ lo maa bẹrẹ sii pe akiyesi wa sawọn nnkan kan, bi apẹẹrẹ,ẹ ni ki n wa ṣe olowo to n fun eeyan lowo tiye ẹ to miliọnu marun ninu ere,e si ni ki n ma lo ọkọ ayọkẹlẹ pasaati iyẹn o bojumu tabi ki Olowo maa wọ aṣọ bi ẹniti wọn bọ aṣọ si lọrun, bi mo ba sọ pe ki wọn jẹ ki n wọ aṣọ ti mo ko wa latile,wọn a ni igberaga ni. Lẹyin iyẹn,ṣe oun nikan lo le ṣe ipo yẹn naa n mu ilara wa koda wọn ma n ya fiimu niwaju ile mi bayii ti wọn o si nii pe mi ṣugbọn o ti yatọ bayii, Mercy Aigbe,Funke Akindele,Kunle Afọlayan ti pe mi sere tiwọn de n sanwo fun mi daadaa.
Ẹ ja ka sọrọ nipa ọjọọbi yin to nbọ lọna, kin ni kawọn eeyan maa reti?
Akọkọ na, mo fẹẹ fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ni toripe labẹ akooso bo ti wu ko ri,sibẹ Ọlọrun dara simi,awọn ẹgbẹ mi kan ti dẹni akọlẹbu,kii ṣe agbara mi lo da mi si,o wu Ọba Aṣẹda ni. Awọn nnkan ti mo ti la kọja ma n jẹ ki ẹru Ọlọrun ba mi, atipe mo fẹẹ kawọn eeyan yẹmisi nigbati mo wa laye, ẹni kawọn to fẹran Kanra wa mu inu ẹ dun nigba to wa laye. Onipele mẹta ni ayẹyẹ to maa waye lọjọ kẹrinlelogun oṣu yii ni NUT Pavillion nilu Ikẹja, ikinni ni tọjọ ibi, ikẹta ni ti sinima kan ti mo ya ti mo si fẹẹ ṣe afihan ẹ, ikẹta ni nnkan ti emi naa le fi ran awujọ lọwọ, iyẹn ni mo pe ni ‘Chief Kanran Fundation’ mo fẹ maa fi kọ awọn eeyan nipa iṣẹ sinima.
Lọdun diẹ sẹyin,ijọba ipinlẹ eko pese owo kan fawọn onitiata,wọn ṣeranwọ owo fawọn agba oṣere, ṣe ẹyin naa wa ninu wọn?
Ara idẹyẹsi ti mo sọ niyẹn, loootọ ni wọn ṣe atojọ orukọ awọn agba ẹgbẹ ṣugbọn wọn o forukọ mi si, wọn mọ ọn mọ ni. Latigbati ti ẹgbẹ oṣelu AD ni mo ti wa ni kọmiti ipolongo ṣugbọn awọn eeyan wa kan na ni wọn lọọ parọ fun wọn loke pe mo ti n ṣiṣẹ fawọn ẹgbẹ alatako, mi o ni darukọ ẹnikankan ṣugbọn wọn mọ ara wọn.
O dabi ẹnipe ajọṣepọ wa laarin ẹyin ati Bayọwa nigba kan ri, wọn ni owo lo daja silẹ?
Aburo ati ọrẹ ni Bayọwa jẹ simi,awọn itan kan wa ta o gbọdọ ma pa bi Ọlọrun ba ti gbe eeyan soke nigba taa fẹ ki ẹni yẹn jabọ. Lasiko ti mo mọ Bayọwa, o lọ mi bẹẹ lo ṣimi lo ṣugbọn ko ṣeka fun mi o, ṣe lo ri ẹwa ogo Ọlọrun lara mi,aain emi ati ẹ ko daru doni ọrẹ ṣi ni wa, kosi ibajẹ ẹ lọwọ mi. Lọjọ kan ni mo lọ ba Funkẹ Akindele ṣiṣẹ,ọmọbinrin naa bu sẹkun lojiji, lo ba ni ki wọn gbe kamẹra kuro, o ni latigba ewe loun ti mọ mi ṣugbọn ko yẹ ki n ṣi wa niru ipo bayii, yatọsi owo iṣẹ mi, o tun fun mi lẹgbọrun lọna ọgọrun naira lọjọ yẹn.
Njẹ ẹyin tẹẹ ni ẹ fi ọgbọn iwe kun tiyin ninu iṣẹ yii ya okoowo sọtọ gẹgẹ bi afojusun ọjọ iwaju?
Ka ma parọ,awa o ro ti okoowo mọ iṣẹ ta n ṣe ṣugbọn awọn ọmọ aye ode oni ti ya a sọtọ,wọn ti n pa owo lori ayelujara. Ka ṣre kaye ki wa nikan lawa mọ oun si lo ko ba wa. Bi a ba fi ẹka okoowo kun iṣẹ wa ni, i ba ti san fun wa ju bayii lọ, iyẹn lawọn Funkẹ Akindele,Fẹmi Adebayọ,Kunle Afọlayan,Mercy Aigbe atawọn ewe iwoyi n ṣe ti ọlọrun si n gba fun wọn.
O ti di ankoo bayii ki wọn ma tọrọ owo fawọn oṣere tiata, ẹyin naa jẹ ọkan ninu awọn ti Agbala Gabriel tọrọ owo fun, ki lo fa a?
Ẹ ja ki n la ọrọ yii ko ye awọn eeyan daadaa o, wọn o gbe emi lọ tọrọ owo lọdọ Agbala Gabriel o,iṣẹ aanu tọmọkunrin naa n ṣe lo wu mi lori iyẹn lo jẹ ki n bẹrẹ sii ṣadura fun. Emi ni mo fadura ranṣẹ sori afẹfẹ, iyẹn lo ri to fi pe mi. Inu ẹ dun lati ba mi sọrọ, o loun fẹẹ ri mi,idi si niyẹn to fi wa. Ṣọọṣi lo ti wa ba mi ṣugbọn bo ṣe ri mi lo ni ipo yẹn ko lo yẹ ki n wa, lojuẹsẹ lawọn eeyan bẹrẹ sii ran mi lọwọ. Ọkunrin naa lo dabaa lati kọ ile fun mi,emi tiẹ ni ko kọ fun ijọ ọlọrun ṣugbọn awọn to n wo walọjọ yẹn ni ile temi ni ki n lọ kọ,igba yẹn ni mo sọ fun pe mo ni ilẹ. Emi o lọọ ṣagbe o,awọn eeyan dide fun iranlọwọ mi nigba woli ẹlẹyinju aanu naa wa ki mi nile.
Owo ti Agbala Gabriel ba yin gba nkọ, kin lẹ fi ṣe?
Ori ilẹ yẹn naa ni mo na le ṣugbọn ira ni ibẹyẹn, o n ri
Ẹ ko ṣe wa lọọ sibomin-in?
Mo fẹ ki Agbala Gabriel ri nnkan ti mo fowo ṣe nibẹ, koda a tun n pinnu lati ra irinṣẹ fun irọrun iṣẹ wa ṣugbọn owo taa ṣi nilo pọ diẹ nitori ẹ ni mo ṣe fẹẹ da ‘Chief Kanran Fundation’ silẹ lati le ma fi ran awọn eeyan ti wọn nifẹẹ si iṣẹ wa yii lọwọ.
Ni bayii ti ẹgbẹ oṣere tiata ti pin si yẹlẹyẹlẹ,ibo lẹyin fi si?
ẹ jẹ ki n kọkọ ṣe atunṣe lọrọ ọrọ tita, ko si nnkan to n jẹ tiata mọ lati nnkan bi ogoji ọdun sẹyin lo ti ku. Idi nipe ere ori itage ni tiata,ikoko to ba maa jẹ ata lọrọ ẹni to fẹẹ ṣe tiata,idi rẹ yoo gbona
Ki ni wọn wa n ṣe nisinyi?
Kamẹra sọ mi doge lo wa nita bayii ko si tiata mọ, awọn to n ya sinima bayii ni Funkẹ Akindele,Kunlẹ Afọlayan ati Fẹmi Adebayọ. Eeyan kan ṣoṣo lo tun ẹgbẹ ANTP, o gbe odidi ẹgbẹ lọsi ile ẹjọ,o da wọn laamu fun odidi ọdun mẹtadinlogun,wọn rọ ọ wọn bẹẹ ṣugbọn ko gba, gbogbo wa ni a n paara kọọtu nigba naa, idi niyẹn ti a fi da ẹgbẹ TAMPAN silẹ, ṣugbọn bi mo ba fẹẹ sọ ọ gbogbo ẹgbẹ ni mo wa toripe bi mo ba fẹẹ ya iṣẹ ti mo si ri ẹni to danyọ ninu ẹgbẹ kan to wu mi lati lo, mo maa pe o.
Awuyewuye n waye lori ọrọ ẹyin ati Iya Adura,Esther Ajayi, wọn ni ipinya ti de saarin ẹyin ati mama naa pẹlu Iya Rainbow, ki lo faa?
Loootọ mi o mọ Iya Esther Ajayi ri tẹlẹ,Iya Rainbow lo mu wa mọra, wọn ni mama naa fẹẹ ṣe eto kan nilu London,wọn si n fẹ ka polowo nnkan to mu wa mọra niyẹn toripe wọn fẹran ipolowo ti mo ṣe. Mo dupẹ lọwọ wọn gẹgẹ bi Iya Rainbow ti ni ki n ṣe, lẹyin naa ni wọn ko wa lọ silu oyinbo. Ṣeni mo n wo obinrin naa bi Angẹli toripe o ya mi lẹnu pe ẹnikan le ko eeyan ẹgbẹrun marun lọsi ilu oyinbo lẹẹkan ṣoṣo iyẹn ni emi n ro ti mo fi n wo o bi angẹli lokeere iyẹn lawọn eeyan ri ti wọn fi lọ sọ fun mama naa pe mo ni igberaga. Lẹyin ọjọ karun ni wọn ni ileya ṣugbọn mo sọ fun wọn pe mo ṣi ni nnkan ti mo fẹ duro ṣe nilu oyinbo. A ti ṣe ipolowo mi-in taa tun ti jọ lọ si ilu amẹrika ṣugbọn ṣadeede ni mama naa o gbe ipe mi mọ. O ṣee ṣe ko jẹ ọrọ ibajẹ tawọn kan ti sọ fun wọn lo jẹ ki wọn ro bẹẹ ṣugbọn mama daadaa ti ko fẹ iwa idọti ni, koda mo ṣi maa lọ fun Iya Adura ni iwe apejẹ ayẹyẹ ọjọọbi mi.
Bawo lo ṣe ma n ri lara yin bẹẹ ba ranti pe awọn eeyan n ṣe ilara yin?
Ẹẹmẹfa ọtọọtọ ni mama mi bi ibeji gbogbo awọn ibeji naa lo ni Idowu ati Alaba, mẹtadinlogun ni gbogbo wa ṣugbọn awa marun pere la sin iya mi, emi ati Taye mi nikan ni ibeji to ṣẹku fun, ara amiwo ti iya mi ri nidi iṣẹ iranṣẹ niyẹn. Emi naa ti ni idojukọ loriṣiiriṣii paapaa julọ nigbati mo gba iṣẹ iranṣẹ tori naa mi o ri ilara naa gẹgẹ bi nnkan babara,adanwo lasan ni.
Awọn kan ni toripe ẹ fẹ iyawo oniyawo ni wọn ṣe ni kẹẹlọ rọ ọ kun sile, ṣe lootọ ni?
Kosi nnkan ti wọn o le fi lọ ẹniti wọn ba rii pe awọn obinrin fẹran ẹ, ṣugbọn ko pẹ ti wọn parọ naa mọ mi lọkọ obinrin naa yọju to sọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ ṣugbọn ko si bi eeyan ṣe n gbayi niwaju onilara
Njẹ ọmọ yin kankan ṣeree tiata?
Ọmọ mi kan n ṣe aṣojuloge, ọkan si sọpe ere tiata wu oun, loootọ emi o ni kọmọ kankan ma ṣe e ṣugbọn wọn gbọdọ fi ẹkọ iwe kun ki wọn le rọna lọ, ọrọ iyanju ti mo si tun ni fawọn ipẹẹrẹ ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ niyẹn.
No comments:
Post a Comment