Ọkan lara awọn gbajugbaja oṣerebinrin ilẹ Yoruba to ṣẹṣẹ n dide bọ, Zainab Bakare ti fi ẹsun kan akẹgbẹ rẹ, Bọlanle Ninalowo wi pe o fi oju kere oun.
Zainab sọ pe ọrọ ti Ninalowo sọ nigba ti awọn fẹẹ ya fiimu kan wi pe oun ko si ninu awọn toun le fi enu ko lẹnu ba ọkan oun jẹ gidi.
O ni ọrọ ba ọkan oun jẹ debi pe oun ko le gbagbe titi aye, to si tun ni o wa lara awọn ipenija toun koju nidi iṣẹ tiata.
Ninu ọrọ rẹ, o ni
“Bawo ni oṣerekunrin kan ṣe maa wo iru emi ṣuṣu to si maa sọ pe awọn to wa ni ipo nla (A-list) nikan loun le fi ẹnu ko lẹnu?
“Nitori pe gbogbo ibi ti wọn ba ti fi ọrọ wa mi lẹnu wo ni mo ti maa n sọ ọ. Ọrọ naa dun mi wọnu ara.
“Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe emi lo sọ fun funra rẹ, oludari ere lo sọ fun, wi pe oun ko le fi ẹnu ko mi lẹnu.
“Mi o le gbagbe ọrọ naa, nitori pe gbogbo ibi ti mo ba ti ni ifọrọwanilẹnuwo ni mo ti maa n sọ, o si maa n ro kangokango lori mi”.
No comments:
Post a Comment