Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkan lara awọn ilu mọ-ọn-ka sọrọsọrọ niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ kika iroyin lede Yoruba fun ọgbọn ọjọ gbako.
Ọjọ kini, oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni Angel Ajayi, Ọmọ Baba Ẹ gbe mi niluu Imaṣayi bẹrẹ kika iroyin lede Yoruba, lati jẹ ki awọn ololufẹ rẹ mọ pe ko si nnkan toun ko le ṣe.
Wayi o, ọkan pataki lara awọn oloye niluu Ijẹja, Abẹokuta, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki-Olu ti ṣabẹwo koriya fun Angel Ajayi.
Nibi abẹwo ọhun ti Ajiki-Olu ṣe lopin ọsẹ to kọja yii, lo ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn ogo pataki nidi iṣẹ redio ni Ajayi.
O ni iwuri nla Angel jẹ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lati fi itan tuntun balẹ, eyi ti ko ṣẹlẹ ri lagbaye, fun idi eyi, oun nilo lati gboriyin fun.
Siwaju sii lo sọ pe iru eyi ko ṣẹlẹ ri, nitori pe mi o gbọ ri pe eeyan kan ṣoṣo da ka iroyin Yoruba fun oṣu gbako nileeṣẹ redio kan ṣoṣo lai sinmi.
O loun mọ pe ko rọrun lati wa ni ibi iṣẹ fun oṣu kan lai lọ sile, ṣugbọn to loun nigbagbọ pe Ọlọrun yoo tubọ gbe e leke nidi iṣẹ to yan laayo.
Bẹẹ lo ṣe ileri pe oun yoo tubọ maa gbaruku ti gbogbo igbesẹ ti ọkunrin naa ba n gbe, fun idagbasoke ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria lapapọ.
Angel ninu ọrọ tiẹ dupẹ lọwọ Ajiki-Olu fun bo ṣe wa ṣe abẹwo sii, to si loun ko nii gbagbe rẹ lailai.
Ọkan pataki lara awọn alakoso ileeṣẹ redio Family FM ti Angel Ajayi ti n ka iroyin naa, Oloye Moruph Adegboyega ti ọpọ mọ si Ọmọ-Ọdọ Agba ninu ọrọ tiẹ sọ pe iṣẹ nla Angel n ṣe nitori ti oun ko ri iru rẹ ri.
Bẹẹ lo sọ pe gbogbo igba loun n gbadura aṣeyọri fun un lati pari rẹ layọ, to si tun fi anfaani naa dupẹ lọwọ Ajiki-Olu fun ifẹ to ni si gbogbo sọrọsọrọ n'ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment