Ile-ẹjọ ju lanlọọdu sẹwọn gbere lẹẹmeji l'Ekoo, awọn ọmọ ayalegbe rẹ lo fipa ba laṣepọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 21, 2023

Ile-ẹjọ ju lanlọọdu sẹwọn gbere lẹẹmeji l'Ekoo, awọn ọmọ ayalegbe rẹ lo fipa ba laṣepọ


Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ ati iwa ipa, Sexual Offences and Domestic Violence Court to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Ekoo ti ju baba arugbo, ẹni ọdun marundinlaadọrin kan, Igwe Ambrose sẹwọn gbere lẹẹmeji ọtọọtọ lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Onidajọ Abiọla Ṣọladoye ti lo ju baba naa sẹwọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọmọdebinrin ọmọ ọdun meje ati ọmọdebinrin ọmọ ọdun mọkanla ti wọn jẹ ọmọ ayalegbe Igwe ni wọn lo fipa ja ibale wọn lasiko ti awọn obi wọn ko si nile.
 
Awọn ẹri aridaju ti wọn l'awọn agbefọba fi silẹ niwaju ile-ẹjọ, lo mu ki Onidajọ Ṣọladoye paṣẹ pe ki baba naa lọ lo eyi to ku nigbesi aye rẹ lọgba ẹwọn.
 
Awọn ọmọ naa lo tu aṣiri fun mama wọn nipa bi baba onile wọn ṣetẹ wọn lọmu, to si tun fi ika ro wọn labẹ.
 
Ẹsun naa ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 135 ati 261 ninu iwe ofin ọdaran ti ọdun 2015 nipinlẹ Ekoo.
 
Ẹlẹrii mẹrin ọtọọtọ la gbọ pe wọn jẹri baba naa lori ẹsun ti wọn lo ṣe laarin oṣu kini si oṣu kẹfa, ọdun 2021 lagbegbe Shagari Estate, Ipaja nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI