Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti kẹyin patapata ti gbogbo awọn to n tọrọ baara l'awọn oju popona ati agbegbe to fi mọ igberiko to wa nipinlẹ naa.
Ijọba sọ pe gbogbo awọn to n tọrọ baara kaakiri yii ni wọn n doju ti ipinlẹ naa kaakiri, pẹlu iwa i ko bojumu naa.
Kọmiṣanna fọrọ idagbasoke ọmọniyan, Social Development nipinlẹ naa, Ọnarebu Ọpẹyẹmi Oluwakẹmi Afọlaṣade lo eyi di mimọ lasiko ti wọn n pari lile awọn to n tọrọ baara naa kuro.
Ọnarebu Afọlaṣhade sọ pe gbogbo awọn to n tọrọ baara ọhun ni wọn n fi ojoojumọ pọ si, ti ko si sẹni ti wọn ko le tọrọ owo lọwọ rẹ, eyi to ni iwa naa ko bojumu to laaarin ilu to n fẹ ilọsiwaju.
Siwaju sii lo sọ pe awọn miran maa n lo anfaani ipenija kekere ti wọn ni lati maa fi tọrọ baara kiri, dipo ki wọn wa iṣẹ ti wọon yoo ṣe.
O wa l'awọn ko ni gba iwa naa mọ laarin igboro ati igberiko to wa nipinlẹ naa, ati pe ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo ki ọwọ abamọ bọ ẹnu.
No comments:
Post a Comment