Ijọba apapọ bẹrẹ ipade ikọkọ pẹlu NLC ati TUC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 15, 2023

Ijọba apapọ bẹrẹ ipade ikọkọ pẹlu NLC ati TUC


Ijọba apapọ orilede Naijiria ti bẹrẹ ipade ikọkọ pẹlu awọn alakoso ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Labour Union ati Trade Union Congress lori iyanṣẹlodi ti wọn gun le.


Ọfiisi oludamọran agba pataki lori ọrọ eto aabo, National Security Adviser, Nuhu Ribadu ni ipade naa ti n lọ lọwọ.

Minisita fọrọ oṣiṣẹ, Simon Bako Lalong, Minisita fọrọ ipinlẹ, Ọnarebu Nkeiruka Onyeajeocha  ni wọn wa nibi ipade ọhun.

Aarẹ ẹgbẹ TUC, Kọmureedi Festus Osifo; akọwe apapọ fẹgbẹ NLC, Emmanuel Ugboaja atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣiṣẹ miran ko gbẹyin nibi ipade ọhun.
 
Ọjọ kẹrinla, oṣu yii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ bẹrẹ iyanṣẹlodi naa, lẹyin ti wọn sọ pe awọn kan lu Aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero nipinlẹ Imo lọjọ kini, oṣu kọkanla, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI