Gomina Kwara bawọn ọmọ ijọ C&S kẹdun iku Baba Aladura - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 13, 2023

Gomina Kwara bawọn ọmọ ijọ C&S kẹdun iku Baba Aladura


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku alakoso ati olori ijọ Cherubim and Seraphim Movement Worldwide, Ọmọwe Samuel Adefila Abidoye ti wọn tun n pe ni Baba Aladura.

Ninu atẹjade ibanikẹdun ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ s'awọn mọlẹbi Baba Aladura ati gbogbo ọmọ ijọ C&S, AbdulRazaq ni baba naa lo igbesi aye rẹ daadaa.
 
O ni oloogbe naa fi ipo rẹ mu idagbasoke ba ẹsin jakejado orileede Naijiria ati gbogbo agbaye.
 
Bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI