Gomina AbdulRazaq tun yan awọn amugbalẹgbẹ ati oludamọran pataki tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 13, 2023

Gomina AbdulRazaq tun yan awọn amugbalẹgbẹ ati oludamọran pataki tuntun


Gomnina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu iyansipo awon amugbalẹgbẹ ati oludamọran pataki tuntun, leyi to ti yan Ọmọwe Adetọla Ariyikẹ Salau gẹgẹ bi oludamọran pataki lori ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2023, o sọ pe iṣẹ awọn eeyan naa bẹrẹ loju ẹsẹ, ati pe wọn gbọdọ lo ipo wọn lati fi mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa.
 
Ọmọwe Salau, ọmọ bibi ilu Ifẹlodun jẹ ogbontarigi ninu ẹkọ imọ sayẹnsi, tẹkinọlọji, imọ ẹrọ ati iṣiro, iyẹn Science, Technology, Engineering, and Mathematics (STEM).
 
Bakan naa lo tun ti kọ oriṣiriṣi iwe pataki to ṣe koko ni awọn ẹka iṣẹ to yan laayo bii STEM is Key; STEM Activities in Algebra Geometry and Personal Finance; ati STEM Activities fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama.

Titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023, Ọmọwe Salau jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Ekoo lori ọrọ eto ẹkọ.
 
Awọn miran tun ni Alaaji Saadu Salahu, gẹgẹ bii oludamọran pataki agba ati olugbaninimọran.
 
Ọgbẹni Kolo Majin Isaiah, gẹgẹ bii oludamọran pataki lori iroyin ati agbenusọ.
 
Bakan naa ni Gomina tun yan Salihu Jemilat (Special Assistant, SDGs); Abdulmumini Kane Habibat (Technical Assistant, Grassroots Empowerment); Ahmed Usman Babakano (Special Assistant, Non-Governmental Affairs); Lawal Abimbola Monsurat (Senior Special Assistant, Women Mobilization); AbdulKareem Alimat Motunrayo (Technical Assistant, Grassroots Empowerment); Falilat Saka (Technical Assistant, Grassroots Empowerment); Abdullateef Atolagbe Adebara (Special Assistant, Humanitarian Affairs); Mindadi Umar Ndagi (Senior Special Assistant, Social Development); Isiaka Yakubu Agodi (Senior Special Assistant, Grassroots Sensitisation). 

Awọn yooku ni: Alashi Obasanjo (SSA Domestic Affairs); Caleb Ono Bobi (SSA, Non-Indigenes Relations); Comrade AbdulKareem Onagun (SSA Labour); Engineer Yusuf M.O. (SSA Infrastructure); Abdulmutalib A. Shittu (SSA Geographical Information Service); Moshood Tayo Gobir (SA Security); Issa Isiaka Jega (SA Intercommunity Relations, Hausa); Dr. Rabiat Alabere (SA & Focal Person National Social Investment Programme); Soliu Habeeb Babaoloye (Special Assistant, Special Needs); Chukwugozie Angus Igwebuike (Special Assistant Inter-Community Relations, Igbo); and AbdulHameed Ibrahim Labaeka (SA, Artist).

Siwaju sii ni gomina tun kede Ọlamilekan Mukail Aileru gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki lori eto aṣilo oogun; Kayọde Ishola gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ pataki lori imọ igbaode (Digital Innovation)

Bakan naa tun ni Ogundele Joseph Olabisi (Special Assistant Local Community Outreach); Ajayi Peter Femi (Special Assistant Social Mobilization); Olateju Rashidat (Special Assistant Urban Markets); and Muhammed Abdullahi (Special Assistant Inter-Community Relations, Fulani).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI