Gomina AbdulRazaq ba akọwe ẹgbẹ CAN ni Kwara kẹdun iku baba rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 17, 2023

Gomina AbdulRazaq ba akọwe ẹgbẹ CAN ni Kwara kẹdun iku baba rẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba akọwe ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹni, Christian Association of Nigeria (CAN), Apostle Shina Ibiyẹmi kẹdun baba rẹ, Apostle (Barr.) Moses Ibiyẹmi.

Moses Ibiyẹmi lo jade laye lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii lẹyin aisan rampẹ.

Ṣaaju iku oloogbe, Ibiyẹmi ni kọmiṣana f'ọrọ eto iṣuna n'ipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina Shaba Lafiagi.

AbdulRazaq ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ti ko ipa rere ninu idagbasoke ati ilọsiwaju Kwara nipa ọkan iwa rere rẹ.

Nigba to n ba mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, AbdulRazaq tun ba ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti baba ọhun ko to ku kẹdun.

Bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oku rẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI