Ganiyu fun ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun loyun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 23, 2023

Ganiyu fun ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun loyun l'Abẹokuta


Boroboro ni baale ile kan, n ka ni teṣan ọlọpaa ẹkun Adatan to w aniluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun nigba tọwọ palaba rẹ segi lori ẹsun wi pe o fun ọmọ bibi inu rẹ loyun.
 
A gbọ pe o pẹ ti Ganiyu ti n ko ibasun fun ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, ko to di pe iyẹn loyun mọ ọn lọwọ.
 
Wọn nigba tọmọ ọhun rii pe oun ti loyun, lo ṣalaye fun baba rẹ wi pe omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu, oun ti loyun.
 
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Ganiu ti mu ọmọ naa lọ si ile itaja ogun lati ra ogun ti yoo fi ṣẹyun naa fun un, ki aṣiri ma ba a tu sita.
 
Wọn ni Ganiyu to n gbe lagbegbe Mọkọla Isalẹ Tapa naa sọ f'awọn oṣiṣẹ ile itaja ogun naa pe ẹnikan lo fun un loyun ti ko si gba a, ati pe oun ko fẹ oyun ẹsin fun ọmọ oun.
 
Nigba ti ọmọ ọhun ri i pe igbesẹ ti baba oun gbe naa ko dara to, lo jẹ ko sọrọ naa f'awọn ara adugbo ti wọn n gbe, ti wọn si lawọn yẹn lo lọ ranṣẹ pe awọn ọlọpaa ti wọn fi lọ gbe Ganiu nile.
 
A tiẹ gbọ pe Ganiu kọkọ sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa oyun osẹ mẹtalelogun ti ọmọ oun ni, ṣugbọn nigba to rii pe aṣiri ti tu kọja ohun ti wọn le daṣọ aṣiri bo, lo jẹ ko bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ.
 
Ọmọlọla Ọdutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lo fi ye wa pe awọn ara adugbo lo lọ fi ọrọ ọhun to alaga adugbo leti.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe alaga adugbo lo lọ fọrọ naa to ọlọpaa leti, ki wọn to lọ gbe e.
 
Bẹẹ lo sọ pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI