Ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo lorilede Naijiria, National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC) ti parọwa si awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun awọn ayederu abẹrẹ ti wọn n gba lasiko yii.
Wọn ni abẹrẹ kan wa ti wọn n pe ni Meronem 1g Injection ti awọn kan n gbe kaakiri Naijiria lasiko yii, nitori pe ayederu rẹ ti pọ nita.
Alakoso agba fun ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisọla Adeyẹye lo pariwo naa sita niluu Abuja, lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tuside.
O ni ileeṣẹ Marketing Authorization Holder (MAH), Pfizer, lo ta wọn lolobo nipa ogun naa ti wọn n ko kaakiri, eyi to lo ṣee ṣe ko ṣe akoba fun araalu to ba gba a.
Siwaju sii lo sọ pe awọn nọmba to wa lara ogun naa yatọ si awọn eyi to jẹ ojulowo pẹlu nọmba 2A21F11 ati awọn eyi to kangun si ipele to gbẹyin, 4A21I17.
No comments:
Post a Comment