Gbajugbaja olorin takasufee nni, ọmọ Fẹmi Ọtẹdọla, Florence Ọtedọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si DJ Cuppy ti gba awọn ọdọ lamọran lati iṣọra fun awọn ti wọn n nifẹẹ.
DJ Cuppy lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara ti 'X' rẹ laipẹ yii.
O ni ọgba ẹwọn to buru julọ lati gbe lagbaye ni idile ti ko si alaafia.
Ninu ọrọ rẹ, o ni “ọgba ẹwọn to buru julọ lagbaye ni ile ti ko si alaafia ati ifọkanbalẹ.
“Ṣọra fun awọn ti ẹ fẹẹ gbe ifẹ yin le lọwọ.”
No comments:
Post a Comment