Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ ti gbe igbimọ dide lati gbogun ti bi awọn alaṣọ adirẹ ṣe n ta aṣọ adirẹ ti wọn n ko wọle sorileede Naijiria lati China.
Ọba Gbadebọ sọ pe opin ti de ba tita awọn aṣọ adirẹ ti orileede China niluu Abẹokuta, nitori pe o n ko itiju nla ba wọn.
Kabiyesi ni ẹnikẹni ko gbọdọ ta aṣọ Adirẹ China mọ ninu ọja Adirẹ ti Itoku ati Aṣero, paapaa kaakiri ilu Abẹokuta lapapọ.
O ni ilu Ẹgba lo ni aṣọ Adirẹ, nitori pe ibẹ lo ti bẹrẹ lorileede Naijiria, ko to di pe awọn kan lọ bẹrẹ sii ṣe ayederu rẹ, ṣugbọn to sọ pe awọn to n ko aṣọ ilẹ miran wọle lati fi tako ojulowo aṣọ wọn fẹẹ dabaru iṣẹṣe ilu Ẹgba ni.
Nigba to n sọrọ ni Aafin rẹ to wa ni Ake niluu Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii, Alake sọ pe aṣọ Adirẹ China n ṣakoba fun eto ọrọ aje ilu Ẹgba, ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria lapapọ, to si ni opin gbọdọ de ba.
Alake wa rọ igbimọ tuntun naa lati ṣiṣẹ iwadii kikun nipa ibi ti wọn ti n ṣe ayederu aṣọ Adirẹ ti wọn n ko wa saarin ọja naa, ati pe o n ṣakoba fun airiṣẹ ṣe awọn ọdọ.
O ni tita aṣọ Adirẹ laarin ọja niluu Abẹokuta ti sọ ọpọ ọdọ di alainiṣẹ lọwọ, to si loun ko le kawọ gbera lati maa wo wọn niran.
Giwa Obinrin ilu Ẹgba, Hajia Mọdinat Adegbitẹ, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ ọhun ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe aṣọ adirẹ China ti fẹẹ le ojulowo aṣọ Adirẹ wọle, ko si dohun igbagbe patapata.
O gbe oriyin fun Kabiyesi fun bo ṣe dide lati gbogun ti awọn ayederu aṣọ Adirẹ ti awọn alaimọkan n wọ kaakiri, toun naa si sọ pe awọn yoo gbogun ti daadaa.
Mojibade ilu Ẹgba, Ọmọbabinrin Comfort Ọmọtade ninu ọrọ tiẹ sọ pe Aṣọ Adirẹ ati apata Olumọ nikan ni ohun pataki ti gbogbo agbaye mọ ilu Ẹgba mọ, to si ni wọn gbogbo daabo bo wọn.
O ni awọn ko ni faaye gba ayederu aṣọ Adirẹ ati aṣọ Adirẹ China mọ ninu awọn ọja Adirẹ bii Itoku ati Aṣero to wa niluu Abẹokuta.
Ninu ọrọ tiẹ, Arabinrin Funṣọ Idowu toun naa jẹ ọkan lara awọn igbimọ yii ṣeleri wi pe awọn yoo ṣe ojuṣe wọn daadaa lati rii pe ogo ilu Ẹgba pada bọ sipo to yẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Arabinrin Funṣọ Idowu toun naa jẹ ọkan lara awọn igbimọ yii ṣeleri wi pe awọn yoo ṣe ojuṣe wọn daadaa lati rii pe ogo ilu Ẹgba pada bọ sipo to yẹ.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn yoo gbe ipolongo kalẹ lati fi to araalu leti nipa didẹkun rira ayederu aṣọ Adirẹ, paapaa awọn ti China.
Siwaju sii, Ọmọbabinrin Adejọkẹ Ṣomoye toun jẹ akọwe igbimọ ọhun ninu ọrọ tiẹ sọ pe ojuṣe awọn ni lati daabobo aṣa, iṣe ati aami idanimọ ilu Ẹgba, to si ni gbogbo ohun ti yoo ba gba lawọn ṣetan lati fun un.
Ṣọmoye ni awokọṣe ni ilu Ẹgba jẹ laarin awọn ilu to ku lorileede Naijiria, to si ni lara awọn ilu ti Ọlọrun yọnu si pupọ ni ilu Ẹgba jẹ nipa awọn ohun amuṣọrọ.
Oloye agba Oluyinka Kufilẹ ni alaga igbimọ naa; nigba ti awọn bii Oloye Alani Bankọle, to jẹ Apena ilu Ẹgba wa nibi eto naa.
No comments:
Post a Comment