Akẹkọọ mẹfa gba awọọdu eto ẹkọ ọfẹ ati miliọnu mẹfa naira ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 20, 2023

Akẹkọọ mẹfa gba awọọdu eto ẹkọ ọfẹ ati miliọnu mẹfa naira ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi ẹbun miliọnu mẹfa naira ta awọn akẹkọọ mẹfa lọrẹ, pẹlu eto ẹkọ ọfẹ titi digba ti wọn yoo fi pari eto ẹkọ wọn.

Opin ọsẹ to kọja yii ni Gomina ṣe ileri naa nigba to n gba ikọ ẹgbẹ akẹkọọ to peregede nibi idije Aarẹ (Presidential Debate Competition) to waye niluu Abuja lalejo.

Nigba to n sọrọ, gomina sọ pe iwuri ni awọn akẹkọọ naa jẹ fun ipinlẹ Kwara pẹlu bi wọn ṣe gbe ogo ipinlẹ naa yọ kaakiri agbaye.

O gbe oṣuba kare fun awọn obi ati olùkọ awọn akẹkọọ naa to fi mọ ajọ Kwara State Universal Basic Education Board (KWSUBEB) for their roles in the feat. 

Akojọpọ awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ bii Mashood Kamaldeen (Government Secondary School, Ilorin East LG); Jatto Ramatallahi (Offa Grammar School, Offa); Jimoh Abayomi Emmanuel (Tanke Community Junior Secondary School, Ilorin South); Emmanuel Chioma (St. Anthony Junior Secondary School, Ilorin East); Dolapo Mariam (Offa Grammar School, Offa); ati AbdulKareem Uswat (Okelele Junior Secondary School Ilorin East). 

Gomina ni akẹkọọ kọọkan yoo gba miliọnu kan naira, bẹẹ tun ni ijọba yoo ran wọn ni ẹkọ ti wọn ba fẹ.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI