Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku Alaaji Usman Baba Patigi, ẹni to jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
AbdulRazaq nigba to n kẹdun iku Baba Patigi, ti ọpọ tun mọ si Samanja, o ni baba naa lo ipo rẹ lati gbe aṣa ati iṣe ipinlẹ naa larugẹ nigba aye rẹ.
O ni ọkan pataki lara awọn to gbe ogo iṣẹ tiata ẹkun Ariwa ti wọn n pe ni Kanniwood larugẹ ni oloogbe naa jẹ, ati pe o tun jẹ atọna gidi.
AbdulRazaq ni titi aye l'awọn yoo maa ranti rẹ fun ipa ree to ko, gẹgẹ bi Ọmọọba niluu Patigi, to si tun fi ipa rere lelẹ nidi iṣẹ tiata naa.
Nigba to n b'awọn mọlẹbi rẹ kẹdun, o gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment