AbdulRazaq ba awọn aṣofin APC yọ lori aṣeyọri ile-ẹjọ kotẹmilọrun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 29, 2023

AbdulRazaq ba awọn aṣofin APC yọ lori aṣeyọri ile-ẹjọ kotẹmilọrun


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC yọ lori aṣeyọri ti wọn ṣe nile ẹjọ kotẹmilọrun, to fi mọ gbigba ẹkun Odo-Ogun to wa nijọba ibilẹ Oyun.

Bi wọn ṣe gba ijọba ibilẹ Oyun pada naa ti jẹ ki awọn aṣofin APC gba ijokoo mẹrinlelogun nile igbimọ aṣofin.

Gomina tun ki Ọnarebu Rukayyat Shittu ti ẹkun Owode/Onire (Asa); Ọnarebu Razaq Owolabi (Shaare/Oke Ode; ati Ọnarebu Atoye Yusuf Musa ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da lare.
 
O ni aṣeyọri naa fi igboya ati igbagbọ araalu ati ijọba mulẹ, ati pe ẹgbẹ mu awọn to yẹ s'ipo.

Bẹẹ lo sọ pe oun nigbagbọ pe awọn aṣofin naa yoo ṣe daadaa gẹgẹ bi afojusun araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI