Aaye ṣi silẹ fun araalu to ba fẹẹ ṣiṣẹ idagbasoke ilu - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 20, 2023

Aaye ṣi silẹ fun araalu to ba fẹẹ ṣiṣẹ idagbasoke ilu - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe aaye ṣi silẹ fun araalu to ba fẹẹ ran ijọba lọwọ nipa iṣẹ idagbasoke ilu, fun ilọsiwaju ipinlẹ naa.
 
Ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣe iṣẹ ilu ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa, Kwara State Ministry of Works and Transport ninu atẹjade ti wọn gbe sita ni wọn ti sọ pe aaye ti ṣi silẹ fun awọn araalu ti Ọlọrun ba bukun fun lati ran ijọba lọwọ.

Atẹjade ọhun akọwe iroyin ileeṣẹ naa, Sam Bọla Onile fi sita lo ti ni ki ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣiṣẹ idagbasoke lati fi ran ijọba lọwọ wa fi to awọn alakoso ileeṣẹ naa leti.

O ni ki akọsilẹ le wa labẹ ofin ni, kii ṣe nitori nnkan miran, paapaa bo ṣe jẹ ijọba ko le ṣe gbogbo ilu tan, bi ko ṣe nipa iranlọwọ araalu.
 
Bakan naa lo ni ọpọ awọn eeyan ni wọn n ṣiṣẹ ilu lati fi ran ijọba lọwọ, to si jẹ pe wọn kii fi to ijọba leti ko to di pe wọn bẹrẹ, eyi to ni ko yẹ ko ri bẹẹ.
 
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe opopona mẹtalelogoji ni ijọba buwọ lu lati ṣe kaakiri ipinlẹ naa, ati pe ijọba yoo tun buwọ lu awọn opopona miran laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI