Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara tun ti kede Onimọ-ẹrọ Arabinrin Fọlaṣade Ọmọniyi gẹgẹ bi alaga agba fun ileeṣẹ to n ri sọrọ ipawo-wọle n'ipinlẹ naa, iyẹn Kwara State Internal Revenue Service (KW-IRS) fun igba keji.
Bakan naa ni Gomina tun kede gbajugbaja onimọ nipa iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ, Ọlayinka Fafoluyi ti ọpọ awọn eeyan mọ si Solace gẹgẹ bi oludamọran pataki agba (Senior Special Assistant) lori ọrọ iroyin igbalode fun igbakeji, koda pẹlu igbega ni.
Yatọ si awọn meji yii, gomina tun kede Ibraheem Abdullateef, ẹni ọdun mejidinlọgbọn gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki agba lori ọrọ eto ikansira-ẹni (Senior Special Assistant on Communications).
Iyansipo Onimọ-ẹrọ Arabinrin Fọlaṣade Ọmọniyi la gbọ pe o bẹrẹ lati ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ipa ti obinrin naa ko ninu eto idagbasoke ipinlẹ Kwara latigba ti wọn ti yan an ninu oṣu kẹwaa, ọdun 2019 ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin, pẹlu bo ṣe pa owo gidi wọle fun ipinlẹ naa lọna ara ọtọ, koda, ti wọn lo tun di gbogbo alaafo ibi ti owo n sapamọ si.
Bakan naa, ni ti Ọlayinka Fafoluyi, wọn loun ti ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe o polongo ipinlẹ naa kaakiri gbogbo agbaye nipa iroyin igbalode, to si di alaafo to wa laaarin ijọba ati araalu.
Wọn ni gbogbo bi nnkan ṣe n lọ ninu ijọba lo fi n to araalu leti, ti ko si jẹ ki eti ijọba di si ohun to n ṣẹlẹ si araalu, iyẹn nipa awọn iroyin igbalode, ọlọkan-o-jọkan to n gbe sita.
Ipo kan naa yii la gbọ pe Ibraheem Abdullateef di mu ni saa akọkọ iṣakoso Gomina AbdulRazaq, to si ko ipa to jọju gidigidi nibẹ, eyi ti wọn tun fi yan an lẹẹkeji.
No comments:
Post a Comment