Kwara fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọ awọn ọdọ lagbaye lara ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 31, 2023

Kwara fẹẹ ṣayẹyẹ ọjọ awọn ọdọ lagbaye lara ọtọ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq loun ti ṣetan lati ṣayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn ọdọ lagbaye lara ọtọ ni ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti akọwe ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ilọsiwaju awọn ọdọ n'ipinlẹ naa, Oluwafẹmi Samuel Adeoye fi sita, o jẹ ko di mimọ pe gbogbo eto lo ti pari.

O ni gẹgẹ bi kọmiṣanna to n boju to ileeṣẹ to n ri sọrọ ilọsiwaju awọn ọdọ, Ọnarebu Usman Yunusa Lade ṣe sọ pe ọna ọtun ni eto ọdun yii yoo gba waye.


Akori ti wọn pe ayẹyẹ ọdun yii ni "Creativity and Governance: Bridging the Gap".

Gbọngan ayẹyẹ Flower Garden to wa niluu Ilọrin ni akanṣe eto ọhun yoo ti waye l'ọjọ kinni, oṣu kọkanla, ọdun 2023.

Ọnarebu Yunusa Lade sọ pe ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq yoo gbe awọn ọjọgbọn loriṣiriṣi ẹka ileeṣẹ dide lati sọrọ lọjọ naa, nibi ti wọn yoo ti da awọn ọdọ ati alejo lẹkọọ to ye kooro.

O ni ọpọ awọn ọdọ lọkunrin ati lobirin lo wa ti wọn n ṣe daadaa ni oriṣiriṣi ẹka iṣẹ ti onikaluku wọn yan laayo, ti wọn si bọ lọjọ naa.


Lara wọn Hajia Bukọla Adedeji, alakoso ileeṣẹ Kwara Garment Factory; Temi Kọlawọle, alakoso ileeṣẹ Ilorin Innovation Hub; Ọnarebu Bọla Olukoju to jẹ kọmiṣanna f'ọrọ eto ikansira-ẹni; Ọnarebu Damilọla Yusuf-Adelọdun toun jẹ kọmiṣanna f'ọrọ iṣẹ imọ ijinlẹ (Business Innovation and Technology); Ọnarebu Fafoluyi Olayinka (Solace) to jẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode; Aileru Ọlamilekan Mukail, oṣiṣẹ pataki nileeṣẹ Narcotics Clan Lab and Illicit Cannabis Specialist, ti yoo maa sọrọ nipa aṣilo oogun ati ipalara to n ṣe fun awọn ọdọ 

Bakan naa ni awọn bii Maryam Apaokagi (Taooma), to n ṣe ere apanilẹrin lori ayelujara; Haneefah Adam; ati Oluṣọla Abdulrahman yoo wa nibẹ lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI