Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe eto ikera to pe ye, alaafia ati igbayegbadun araalu lo jẹ ijọba oun logun julọ, idi ree toun fi n sa gbogbo ipa lati rii pe nnkan lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
AbdulRazaq lo sọrọ naa lọjọ Ajr, Mọnde, lasiko to ṣe abẹwo oju-mi-to si ọsibitu ijọba, General Hospital to wa niluu Ilọrin lati wo bi nnkan ṣe n lọ.
Abẹwo naa lo ti wo bi awọn irinṣẹ itọju igbalode ti wọn ṣẹṣẹ ra ṣe n ṣiṣẹ si ati bi wọn ṣe n lo wọn.
O ni ko pọn dandan ki awọn eeyan maa lọ gba itọju loke okun mọ niwọn igba ti awọn irinṣẹ ayẹwo ati itọju igbalode ti wa.
No comments:
Post a Comment