Ẹgbẹ́ tó ti di ohun ìgbàgbé ni PDP, ajègbodò tó ń wá ẹni kúnra ni wọ́n - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 11, 2023

Ẹgbẹ́ tó ti di ohun ìgbàgbé ni PDP, ajègbodò tó ń wá ẹni kúnra ni wọ́n - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe ajegbodo to n wa ẹni kunra ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, paapaa n'ipinlẹ naa, nitori pe wọn ti di ohun igbagbe patapata.

AbdulRazaq lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii lati fi tako ẹsun ti PDP fi kan an.

Gomina sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko yẹ koun dahun si ọrọ ẹsun ti PDP fi kan ijọba oun nibi ipade awọn akọroyin ti wọn ṣe, ṣugbọn lati le jẹ ki awọn araalu mọ otitọ, loun yoo ṣe fesi.

O ni ko fi bẹẹ si ọrọ gidi kan toun le fesi si, ṣugbọn bi ko ṣe lati ṣọ ohun ti ẹgbẹ naa jẹ, 'ẹgbẹ to kun fun awọn oloṣelu alaiṣotitọ, ti wọn ṣi gbe ninu ohun to ti kọja'.

Ninu ọrọ rẹ, o ni
"Bi ẹ ba fẹẹ mọ iru iwa ti ẹgbẹ PDP jẹ, ṣe ni ki ẹ lọ farabalẹ gbọ oriṣiriṣi ọrọ ati idahun ti wọn sọ lori ohun kan ṣoṣo to ba ṣẹlẹ, paapaa lori iye owo ti wọn fi silẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019.

"L'ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019, gomina ana, Abdulfatahi Ahmed sọ ninu iwe igbejọba silẹ rẹ ti olori awọn oṣiṣẹ ka wi pe iṣakoso oun fi biliọnu marun-un naira silẹ ninu apo owo ijọba oun, owo naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe owo ori adapada lati ọdọ ijọba apapọ, eyi ti ajọ EFCC gbẹsẹ le ni.

"Bẹẹni, owo to pada tẹ ijọba Kwara lọwọ ninu owo naa di ni igba, to si jẹ ₦4.8bn, eyi ti a ko fi bo rara latigba ti a ti gba ijọba, loorekoore la si n sọ ọ sita.

"Ni ogunjọ, oṣu kin-ni-in, ọdun 2023, gẹgẹ bi iṣe wọn, oloye PDP to tun jẹ kọmiṣanna tẹlẹ f'ọrọ eto iṣuna, Ademọla Banu sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu New Telegraph sọ pe ijọba awọn fi biliọnu mẹjọ ataabọ silẹ ninu apo owo ijọba.

"Lonii, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2023, nibi ipade awọn akọroyin wọn, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Babatunde Mohammed sọ pe biliọnu mẹwaa naira ni awọn fi silẹ lọ. Ewo wa ni ki a gbagbọ ninu ọrọ mẹtẹẹta wọnyi?

"Oun funra rẹ ko sọ pe ijọba awọn fi gbese ọgọrun biliọnu naira silẹ lọ. Awọn ọrọ irọ ati ẹtanjẹ to n kọminu yii ti fi iru iwa to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP han sita, o si wa a pẹlu idi pataki ti awọn araalu Kwara fi kẹyin si wọn lakoko eto idibo meji ọtọọtọ."

Gomina sọ pe ko jẹ tuntun wi pe ẹgbẹ to n yi iye owo oada ni gbogbo igba, ti fi aiṣotitọ wọn han, wọn si ti n jẹ ko di mimọ pe awọn ko kaju oṣuwọn lati ṣakoso ilu.

Fun idi eyi, AbdulRazaq ni ki awọn araalu yago fun wọn patapata, lati ma ba a ṣi wọn lọkan, paapaa to ba de bi ọrọ oṣelu ati iṣejọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI