Ijọba orileede Naijiria ti sọ pe atunṣe ti wọn ṣe lori afara Third Mainland n’ipinlẹ naa ti pari, o ti di ṣee gba fun gbogbo awọn awakọ bayii lai si idiwọ kankan.
Alakoso eto akanṣe iṣẹ apapọ n’ipinlẹ Ekoo, Arabinrin Olukorede Kesha lo fidi rẹ mulẹ lonii, ọjọ Aiku, Sannde, to si ni atunṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe gangan lati mu iṣoro ti awọn awakọ n koju lori afara naa yoo waye ninu oṣu kinni, ọdun 2024.
Kesha sọrọ naa lasiko to n ṣe abẹwo si awọn agbegbe ti atunṣe ti waye lori afara naa ni irọlẹ oni.
Bẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ tii ṣe Tọside to kọja yii ni ijọba kede sita wi pe wọn yoo ti afara naa pa ni oru ọjọ Abamẹta, Satide si oni ọjọ Aiku, Sannde lati ṣe atunṣe to yẹ lori afara naa, fun irọrun araalu.
O ni afara naa ti di ohun ipenija fun igbokegbodo ọkọ, to si di dandan ki wọn tun un ṣe ko to di pe o di nnkan ti agbara ko nii ka mọ.
Siwaju sii lo sọ pe atunṣe to waye yii ni wọn ṣe lati fi mu adinku diẹ ba iṣoro ti awọn awakọ n koju lori afara naa, to si ni atunṣẹ ti yoo fọkan balẹ patapata yoo bẹrẹ ninu oṣu akọkọ, ọdun 2024.
No comments:
Post a Comment