Iroyin ibanujẹ lo wọ orileede Naijiria laaarọ oni, ọjọ Ẹti, Furaide, nigba ti wọn kede iku Alaaji Mansur Nuhu Bamalli, to jẹ aṣoju orileede Naijiria si Morocco.
Alaaji Bamalli, yatọ si pe o jẹ aṣoju Naijiria si Morocco, oun naa tun ni Magajin Garin tiluu Zazzau to wa nipinlẹ Kaduna.
Ọkunrin naa to tun jẹ aburo si Ẹmir tiluu Zazzau ni wọn lo dagbere f’aye lẹni ọdun mejilelogoji siluu Ekoo.
Asiko ti wọn n palẹmọ lati gbe e lọ fun itọju ni ọsibitu to wa lọ si Morocco lo ta teru nipaa.
Oni naa la gbọ pe wọn yoo sinku oloogbe naa ni ilana musulumi, bo tilẹ jẹ awọn mọlẹbi ko tii kede bi eto isinku naa yoo ṣe lọ.
Iyawo kan, ati ọmọ meji ni Bamalli fi silẹ s’aye lọ.
Aarẹ ana ni Naijiria, Muhammadu Buhari lo yan Bamalli l’ọdun to kọja.
Ko si too di pe Buhari yan an, oun ni igbakeji ọga agba ni ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere, iyẹn Ministry of Foreign Affairs.
No comments:
Post a Comment