Agidi ni ijọba Tinubu fi n san owo oṣu oṣiṣẹ, ko si owo mọ - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 20, 2023

Agidi ni ijọba Tinubu fi n san owo oṣu oṣiṣẹ, ko si owo mọ - Ijọba


Ijọba apapọ orileede yii ti sọ pe awọn adojukọ nla l’awọn n doju kọ bayii lati ri owo oṣu awọn oṣiṣẹ san, pẹlu bi awọn eeyan ṣe n fojoojumọ pọ si.

Minisita fọrọ eto iṣuna, iyẹn Budget and National Planning, Atiku Bagudu, lo kọminu, to si pariwo sita wi pe niṣe ni ijọba n la kaka lati ri owo oṣu awọn oṣiṣẹ san, nitori pe ko si owo mọ.

Bagudu nigba to n sọrọ niluu Abuja l’Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii, o rawọ s’awọn ileeṣẹ ati ajọ aladani lati ran wọn lọwọ.

O ni ojoojujmọ ni awọn ọmọ Naijiria n pọ si, to si ni eyi lo n fa airi iṣẹ ṣe lawujọ Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI