Adron Homes bẹrẹ ipolongo aisan jẹjẹrẹ ti ọmu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 2, 2023

Adron Homes bẹrẹ ipolongo aisan jẹjẹrẹ ti ọmu


Gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣowo ilẹ ati ile, Adron Homes ti bẹrẹ ipolongo aisan jẹjẹrẹ ti ori ọmu fun awọn obinrin, lori ọna ti wọn le gba dena arun naa.
 
Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu kẹwaa ọdọọdun ni eto ipolongo fun aisan jẹjẹrẹ ti a mọ si 'Breast Cancer Awareness and Research' kaakiri agbaye maa n waye.

Lara awọn ipa ati ojuṣe idagbasoke ti ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited si maa n ko ni eyi, lati fi ran ilọsiwaju ilu ati orileede lọwọ.
 
Alakoso agba fọrọ eto iṣuna ileesṣẹ Adron Homes, Olori Aderonkẹ EmmanuelKing la gbọ pe o n ṣagbatẹru eto naa lọdọọdun fun awọn obinrin bii tiẹ.
 
Ninu eto naa ni wọn ti maa n ṣayẹwo ọfẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ wọn to jẹ obinrin kaakiri Naijiria, pẹlu erongba lati jẹ ki wọn wa ni ilera pipe.
 
Ileeṣẹ Adron Homes ati ileeṣẹ PinkClinic Nigeria ni wọnm jọ n fọwọsowọpọ gbe eto naa larugẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI