Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣe abẹwo sile ẹkọ Keu ti ijọba ti Kwara State College of Arabic and Islamic Studies to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa lati mọ bi nnkan ṣe n lọ si.
Nibi abẹwo ni gomina ti ba awọn alakoso ile ẹkọ naa ṣe ipade rampẹ lati mọ ipo ti ile ẹkọ ọhun wa, ati bi awọn akẹkọọ ṣe n ṣe si.
Gomina tun ṣe ileri pe oun yoo tubọ maa ṣe iranwọ to ba yẹ lasiko lati rii pe awọn olukọ ati akẹkọọ n jẹ igbadun mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa.
Bakan naa lo gba wọn lamọran lati mu iṣẹ wọn lọkunkundun nipa ifarajin, eyi to le jẹ ki wọn jeere.
No comments:
Post a Comment