Wọn yinbọn pa Machine ati SM nibi ija ọmọ ẹgbẹ okunkun n'Ileṣa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2023

Wọn yinbọn pa Machine ati SM nibi ija ọmọ ẹgbẹ okunkun n'Ileṣa


Ko din ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ti awọn alatako wọn yinbọn pa nile igbafẹ kan to wa ni ikorita Onimọ, ilu Ileṣa, ipinlẹ Ọṣun laipẹ yii, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti jẹ ko di mimọ pe iwadii ti bẹrẹ.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe irọlẹ ọjọ Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii ni iṣẹlẹ ọhun waye nibi ti awọn eeyan ti n gbafẹ wọn nile igbafẹ naa.
 
A gbọ pe ṣadede ni awọn kan ọmọ ẹgbẹ okunkun yawo ile igbafẹ naa, ti wọn si yinbọn pa awọn meji ti awọn naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako.
 
Niṣe ni wọn lọrọ di boolọ o yago lọna, to di pe onikaluku f'ẹsẹ fẹ ẹ, ti ọlọmọ ko si ranti ọmọ rẹ mọ. Awọn meji ti a gbọ pe wọn yinbọn pa ọhun ni wọn pe inagijẹ wọn ni Machine ati SK.
 
Onimọ tiluu Imọ, Ọba Ọlaniyi Agunbiade nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe bọọlu loun n wo lọwọ ninu aafin rẹ ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ, ko to di pe oun bẹrẹ sii gburo ibọn lakọ-lakọ.
 
Kabiyesi ni loju ẹsẹ loun ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa Ijamọ, ti awọn naa ko si fi falẹ rara.
 
Ọba alaye naa sọ pe ẹpa ko boro mọ nigba ti awọn ọlọpaa yoo fi debẹ, nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ṣọṣẹ wọn, wọn si ti na papa bora, ṣugbọn ni awọn ọlọpaa lo pada ko oku awọn meji naa kuro.
 
Yẹmisi Ọpalọla, to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to si ni awọn ti bẹrẹ iwadii nitori pe ija ọmọ ẹgbẹ okunkun lo waye, ti ọwọ si gbọdọ tẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI